Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 7:40-51 BIBELI MIMỌ (BM)

40. Huramu mọ ọpọlọpọ ìkòkò, ó fi irin rọ ọkọ́ pupọ, ó sì ṣe àwọn àwo kòtò. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe parí iṣẹ́ tí ó bá Solomoni ọba ṣe ninu ilé OLUWA.

41. Àwọn iṣẹ́ náà nìwọ̀nyí: Òpó meji, ati àwọn ọpọ́n rìbìtì rìbìtì meji tí ó wà lórí àwọn òpó náà, ati iṣẹ́ ọnà tí ó ṣe sí ara àwo meji tí ó wà lórí ọpọ́n.

42. Àwọn irinwo pomegiranate tí wọ́n tò sí ìlà meji yí ọpọ́n bìrìkìtì bìrìkìtì orí àwọn òpó náà ká, ní ọgọọgọrun-un.

43. Ó ṣe agbada omi mẹ́wàá ati ìtẹ́dìí kọ̀ọ̀kan fún wọn.

44. Ó ṣe agbada omi ńlá kan ati àwọn ère mààlúù mejila tí wọ́n wà ní abẹ́ rẹ̀.

45. Bàbà dídán ni Huramu fi ṣe àwọn ìkòkò ati ọkọ́ ati àwokòtò ati gbogbo ohun èlò inú ilé OLUWA tí ó ṣe fún Solomoni ọba.

46. Ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jọdani tí ó jẹ́ ilẹ̀ amọ̀, láàrin Sukotu ati Saretani, ni ọba ti ṣe wọ́n.

47. Solomoni kò wọn àwọn ohun èlò tí ó ṣe, nítorí wọ́n pọ̀ yanturu. Nítorí náà kò mọ ìwọ̀n bàbà tí ó lò.

48. Solomoni ṣe gbogbo àwọn ohun èlò wọnyi sinu ilé OLUWA: pẹpẹ wúrà, tabili wúrà fún burẹdi ìfihàn;

49. àwọn ọ̀pá fìtílà tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe: marun-un ní ìhà àríwá, ati marun-un ní ìhà gúsù níwájú Ibi-Mímọ́-Jùlọ; àwọn òdòdó, àwọn fìtílà, ati àwọn ẹ̀mú wúrà,

50. àwọn ife ati ọ̀pá tí wọ́n fi ń pa iná ẹnu fìtílà; àwokòtò ati àwo turari, àwo ìfọnná tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe, wọ́n fi wúrà ṣe àwọn ihò àgbékọ́ ìlẹ̀kùn Ibi-Mímọ́-Jùlọ ati ti ìlẹ̀kùn gbọ̀ngàn Tẹmpili náà.

51. Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ọba ṣe parí gbogbo iṣẹ́ kíkọ́ ilé OLUWA, ó kó gbogbo fadaka, wúrà, ati àwọn ohun èlò inú ilé ìsìn, tí Dafidi, baba rẹ̀, ti yà sí mímọ́ wá, ó sì fi wọ́n pamọ́ sinu àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ninu ilé OLUWA.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 7