Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 7:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọdún mẹtala ni Solomoni fi parí kíkọ́ ilé ti ara rẹ̀.

2. Ọ̀kan ninu àwọn ilé tí ó kọ́ sí ààfin náà ni Ilé Igbó Lẹbanoni. Ilé náà gùn ní ọgọrun-un (100) igbọnwọ, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ, ó sì ga ní ọgbọ̀n igbọnwọ. Orí òpó igi kedari, tí wọ́n na ọ̀pá àjà igi kedari lé, ni wọ́n kọ́ ọ lé.

3. Wọ́n to àwọn òpó, tí wọ́n kọ́ ilé yìí lé lórí, ní ìlà mẹta. Òpó mẹẹdogun mẹẹdogun wà ní ìlà kọ̀ọ̀kan. Wọ́n wá na ìtì igi kedari lé àwọn òpó náà lórí.

4. Ìlà mẹta mẹta ni wọ́n to fèrèsé sí, àwọn fèrèsé ilé náà kọjú sí ara wọn ní àgbékà mẹta.

5. Onígun mẹrin ni wọ́n ṣe férémù tí wọ́n fi ṣe àwọn ẹnu ọ̀nà ati fèrèsé ilé náà, wọ́n to àwọn fèrèsé ní ìlà mẹta mẹta ninu ògiri, ni àgbékà àgbékà, lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji ilé náà; wọ́n dojú kọ ara wọn.

6. Ó kọ́ gbọ̀ngàn kan tí ó sọ ní gbọ̀ngàn Olópòó. Gígùn rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ. Ó ní ìloro kan tí wọ́n kọ́ sórí òpó; wọ́n ta nǹkan bò ó lórí.

7. Ó kọ́ gbọ̀ngàn ìtẹ́ kan, níbi tí yóo ti máa dájọ́; igi kedari ni wọ́n fi ṣe ara ògiri rẹ̀ láti òkè délẹ̀.

8. Ó kọ́ ilé tí òun alára óo máa gbé sí àgbàlá tí ó wà lẹ́yìn gbọ̀ngàn bí ó ti kọ́ àwọn ilé yòókù; ó sì kọ́ irú gbọ̀ngàn yìí gan-an fún ọmọ ọba Farao tí ó gbé ní iyawo.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 7