Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 6:26-38 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Ekinni keji wọn ga ní igbọnwọ mẹ́wàá.

27. Ó gbé wọn kalẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn ninu Ibi-Mímọ́-Jùlọ. Àwọn mejeeji na ìyẹ́ wọn tí ó fi jẹ́ pé ọ̀kan ninu àwọn ìyẹ́ Kerubu kinni kan ògiri yàrá ní ẹ̀gbẹ́ kan, ọ̀kan ninu àwọn ìyẹ́ Kerubu keji sì kan ògiri yàrá ní ẹ̀gbẹ́ keji. Ìyẹ́ keji Kerubu kinni ati ìyẹ́ kinni Kerubu keji sì kan ara wọn ní ààrin yàrá náà.

28. Wúrà ni wọ́n yọ́ bo àwọn Kerubu náà.

29. Wọ́n gbẹ́ àwòrán igi ọ̀pẹ, ati ti òdòdó, ati ti Kerubu yípo ara ògiri yàrá tí ó wà ninu ati èyí tí ó wà lóde;

30. wọ́n sì yọ́ wúrà bo ilẹ̀ àwọn yàrá náà.

31. Wọ́n ri ìlẹ̀kùn meji, alápapọ̀, tí wọ́n fi igi olifi ṣe, mọ́ ẹnu ọ̀nà Ibi-Mímọ́-Jùlọ. Àtẹ́rígbà ìlẹ̀kùn náà rí ṣóńṣó ní ààrin,

32. wọ́n gbẹ́ igi ọ̀pẹ, ati òdòdó, ati kerubu sí ara àwọn ìlẹ̀kùn náà; wọ́n sì yọ́ wúrà bò wọ́n patapata: ati igi ọ̀pẹ, ati òdòdó, ati àwọn Kerubu náà.

33. Wọ́n fi igi olifi ṣe férémù ìlẹ̀kùn onígun mẹrin, wọ́n rì í mọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọ gbọ̀ngàn ńlá.

34. Wọn fi igi sipirẹsi ṣe ìlẹ̀kùn meji, ekinni keji ní awẹ́ meji, awẹ́ ekinni keji sì ṣe é pàdé mọ́ ara wọn.

35. Wọ́n gbẹ́ igi ọ̀pẹ, ati òdòdó, ati àwọn kerubu sí ara àwọn ìlẹ̀kùn náà, wọ́n sì fi wúrà bo gbogbo wọn.

36. Bí wọ́n ṣe mọ ògiri àgbàlá inú ilé ìsìn náà ni pé, bí wọ́n bá mọ ìlè òkúta mẹta wọn a mọ ìlè igi kedari kan.

37. Ninu oṣù Sifi, ní ọdún kẹrin ìjọba Solomoni, ni wọ́n fi ìpìlẹ̀ ilé ìsìn náà sọlẹ̀.

38. Ninu oṣù Bulu, ní ọdún kọkanla ìjọba Solomoni ni wọ́n kọ́ ilé ìsìn náà parí patapata, ó sì rí bí wọ́n ti ṣètò pé kó rí gẹ́lẹ́. Ọdún meje ni ó gba Solomoni láti parí rẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 6