Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 6:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí ó di ọrinlenirinwo (480) ọdún tí àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, ní ọdún kẹrin tí Solomoni gun orí oyè ní Israẹli, ní oṣù Sifi, tíí ṣe oṣù keji ọdún náà, ni ó bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ilé OLUWA.

2. Gígùn ilé tí Solomoni kọ́ fún OLUWA jẹ́ ọgọta igbọnwọ, ìbú rẹ̀ jẹ́ ogún igbọnwọ, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ.

3. Yàrá àbáwọlé ilé ìsìn náà gùn ní ogún igbọnwọ, gígùn rẹ̀ ṣe déédé pẹlu ìbú rẹ̀, ó sì jìn sí ìsàlẹ̀ ní igbọnwọ mẹ́wàá níwájú.

4. Ògiri ilé ìsìn náà ní àwọn fèrèsé tí wọ́n fẹ̀ ninu ju bí wọ́n ti fẹ̀ lóde lọ.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 6