Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 5:8-18 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ó ranṣẹ pada sí Solomoni, ó ní, “Mo gbọ́ iṣẹ́ tí o rán sí mi, n óo sì ṣe ohun tí o ní kí n ṣe fún ọ nípa igi kedari ati igi sipirẹsi.

9. Àwọn iranṣẹ mi yóo gé igi náà ní Lẹbanoni, wọn yóo kó wọn wá sí etí òkun. Wọn óo dì wọ́n ní ìdì kọ̀ọ̀kan kí wọ́n lè tù wọ́n gba ojú òkun lọ sí ibikíbi tí o bá fẹ́. Wọn óo tú wọn kalẹ̀ níbẹ̀, wọn óo sì kó wọn fún àwọn iranṣẹ rẹ. Ohun tí mo fẹ́ kí o mójútó ni oúnjẹ tí èmi ati ìdílé mi óo máa jẹ.”

10. Bẹ́ẹ̀ ni Hiramu ṣe tọ́jú gbogbo igi kedari ati igi sipirẹsi tí Solomoni nílò fún un.

11. Ní ọdọọdún, Solomoni a máa fún Hiramu ní ọ̀kẹ́ kan (20,000) òṣùnwọ̀n kori ọkà, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) òṣùnwọ̀n kori òróró dáradára fún ìtọ́jú oúnjẹ fún Hiramu ati àwọn eniyan rẹ̀.

12. OLUWA fún Solomoni ní ọgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀, alaafia sì wà láàrin òun ati Hiramu, àwọn mejeeji sì bá ara wọn dá majẹmu.

13. Solomoni ọba ṣa ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) eniyan jọ lára àwọn ọmọ Israẹli, láti ṣe iṣẹ́ tipátipá.

14. Ó fi Adoniramu ṣe alabojuto wọn. Ó pín wọn sí ọ̀nà mẹta: ẹgbaarun (10,000) ọkunrin ní ìpín kọ̀ọ̀kan. Ìpín kọ̀ọ̀kan a máa ṣiṣẹ́ fún oṣù kan ní Lẹbanoni, wọn á sì pada sílé fún oṣù meji.

15. Solomoni sì tún ní ọ̀kẹ́ mẹrin (80,000) ọkunrin tí ń fọ́ òkúta ní agbègbè olókè; ati ọ̀kẹ́ mẹta ó lé ẹgbaarun (70,000) ọkunrin tí ń ru òkúta tí wọ́n bá fọ́.

16. Ó yan ẹẹdẹgbaaji ó lé ọọdunrun (3,300) ọkunrin, láti máa bojútó iṣẹ́ àwọn òṣìṣẹ́.

17. Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Solomoni ọba, wọ́n fọ́ òkúta ńláńlá, wọ́n sì gbẹ́ wọn fún mímọ ìpìlẹ̀ ilé OLUWA náà.

18. Àwọn òṣìṣẹ́ Solomoni ati ti Hiramu, ati àwọn ọkunrin mìíràn láti ìlú Gebali ni wọ́n gbẹ́ òkúta, tí wọ́n sì la igi fún kíkọ́ ilé OLUWA.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 5