Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 4:27-34 BIBELI MIMỌ (BM)

27. Alákòóso kọ̀ọ̀kan níí máa tọ́jú nǹkan jíjẹ tí Solomoni ọba ń lò fún ara rẹ̀ ati fún gbogbo àwọn tí ń jẹun ní ààfin rẹ̀; alákòóso kọ̀ọ̀kan sì ní oṣù tí ó gbọdọ̀ pèsè nǹkan jíjẹ, láìjẹ́ kí ohunkohun dín ninu ohun tí ọba nílò.

28. Wọn a sì máa mú ọkà baali ati koríko wá fún àwọn ẹṣin tí ń wa kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹṣin tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́. Olukuluku a máa mú ohun tí wọ́n bù fún un wá sí ibi tí wọ́n ti nílò rẹ̀.

29. Ọgbọ́n ati òye tí Ọlọrun fún Solomoni kọjá sísọ, ìmọ̀ rẹ̀ sì kọjá ìwọ̀n.

30. Solomoni gbọ́n ju àwọn amòye ìhà ìlà oòrùn ati ti Ijipti lọ.

31. Òun ni ó gbọ́n jùlọ ní gbogbo ayé. Ó gbọ́n ju Etani ará Ẹsira lọ, ati Hemani, ati Kakoli, ati Dada, àwọn ọmọ Maholi. Òkìkí rẹ̀ sì kàn káàkiri gbogbo agbègbè tí ó yí i ká.

32. Ẹgbẹẹdogun (3,000) ni òwe tí òun nìkan pa, orin tí òun nìkan kọ sì jẹ́ marunlelẹgbẹrun.

33. Ó sọ nípa igi, ó bẹ̀rẹ̀ láti orí igi kedari ti ilẹ̀ Lẹbanoni, títí kan Hisopu tí ó ń hù lára ògiri. Ó sọ nípa àwọn ẹranko, ati àwọn ẹyẹ, àwọn ohun tí ń fi àyà fà ati àwọn ẹja.

34. Àwọn eniyan sì ń wá láti oniruuru orílẹ̀ èdè, ati láti ọ̀dọ̀ àwọn ọba ní gbogbo ayé, tí wọ́n ti gbúròó nípa ọgbọ́n rẹ̀, wọn á wá tẹ́tí sí ọgbọ́n rẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 4