Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 4:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Solomoni jọba gbogbo ilẹ̀ Israẹli,

2. Orúkọ àwọn olórí ninu àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ nìwọ̀nyí: Asaraya, ọmọ Sadoku ni alufaa.

3. Elihorefi ati Ahija, meji ninu àwọn ọmọ Ṣiṣa ni akọ̀wé ní ààfin ọba. Jehoṣafati, ọmọ Ahiludi ni olùtọ́jú àwọn ìwé àkọsílẹ̀.

4. Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, ni balogun. Sadoku ati Abiatari jẹ́ alufaa,

5. Asaraya, ọmọ Natani, ni olórí gbogbo àwọn òṣìṣẹ́. Sabudu, ọmọ Natani, ni alufaa ati olùdámọ̀ràn fún ọba.

6. Ahiṣari ni olùdarí gbogbo àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ninu ààfin. Adoniramu ọmọ Abida ni olórí àwọn tí ń kó àwọn eniyan ṣiṣẹ́ tipátipá.

7. Solomoni yan àwọn mejila gẹ́gẹ́ bí alákòóso ní ilẹ̀ Israẹli. Àwọn ni wọ́n ń ṣe ètò àtikó oúnjẹ jọ ní agbègbè wọn, fún ìtọ́jú ọba ati gbogbo àwọn tí ń gbé ààfin ọba. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn á máa pèsè oúnjẹ fún oṣù kọ̀ọ̀kan ninu ọdún kọ̀ọ̀kan.

8. Orúkọ àwọn alákòóso mejeejila ati agbègbè tí olukuluku wọn ń mójú tó nìwọ̀nyí: Benhuri ní ń ṣe àkóso agbègbè olókè Efuraimu;

9. Bẹndekeri ni alákòóso fún ìlú Makasi, ati Ṣaalibimu, ìlú Beti Ṣemeṣi, Eloni, ati Beti Hanani.

10. Benhesedi ní Aruboti ni alákòóso fún ìlú Aruboti, ati Soko, ati gbogbo agbègbè Heferi.

11. Bẹnabinadabu, ọkọ Tafati, ọmọ Solomoni, ni alákòóso gbogbo agbègbè Nafati-dori.

12. Baana, ọmọ Ahiludi, ni alákòóso ìlú Taanaki, ati ti Megido, ati gbogbo agbègbè Beti Ṣeani, lẹ́bàá ìlú Saretani, ní ìhà gúsù Jesireeli ati Beti Ṣeani; títí dé ìlú Abeli Mehola títí dé òdìkejì Jokimeamu.

13. Bẹngeberi ni alákòóso ìlú Ramoti Gileadi, (ati àwọn ìletò Jairi, ọmọ Manase, tí ó wà ní ilẹ̀ Gileadi, ati agbègbè Arigobu, ní ilẹ̀ Baṣani. Gbogbo wọn jẹ́ ọgọta ìlú ńláńlá tí wọn mọ odi yíká, bàbà ni wọ́n sì fi ṣe ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn ẹnubodè wọn.)

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 4