Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 3:18-28 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Ọjọ́ kẹta tí mo bí ọmọ tèmi ni obinrin yìí náà bí ọmọkunrin kan. Àwa meji péré ni a wà ninu ilé, kò sí ẹnìkẹta pẹlu wa.

19. Ní alẹ́ ọjọ́ kan, ó sùn lé ọmọ tirẹ̀ mọ́lẹ̀, ọmọ tirẹ̀ bá kú.

20. Ó bá dìde ní ọ̀gànjọ́ òru, ó wá jí ọmọ tèmi gbé ní ẹ̀gbẹ́ mi nígbà tí mo sùn lọ, ó tẹ́ ẹ sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀, ó sì tẹ́ òkú ọmọ tirẹ̀ sọ́dọ̀ mi.

21. Nígbà tí mo jí ní ọjọ́ keji láti fún ọmọ ní oúnjẹ, mo rí i pé ó ti kú. Ṣugbọn nígbà tí mo yẹ̀ ẹ́ wò fínnífínní, mo rí i pé kì í ṣe ọmọ tèmi ni.”

22. Ṣugbọn obinrin keji dáhùn pé, “Rárá! Èmi ni mo ni ààyè ọmọ, òkú ọmọ ni tìrẹ.”Ekinni náà tún dáhùn pé, “Irọ́ ni! Ìwọ ló ni òkú ọmọ, ààyè ọmọ ni tèmi.”Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí jiyàn níwájú ọba.

23. Nígbà náà ni Solomoni ọba dáhùn, ó ní, “Ekinni keji yín ń wí pé, òun kọ́ ni òun ni òkú ọmọ, ààyè ni tòun.”

24. Ọba bá ranṣẹ pé kí wọ́n mú idà kan wá. Nígbà tí wọ́n mú un dé,

25. ó pàṣẹ pé kí wọ́n la ààyè ọmọ sí meji, kí wọ́n sì fún àwọn obinrin mejeeji ní ìdajì, ìdajì.

26. Ọkàn ìyá tí ó ni ààyè ọmọ kò gbà á, nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí ọmọ rẹ̀, ó wí fún ọba pé, “Kabiyesi, gbé ààyè ọmọ yìí fún ekeji mi, má pa á rárá.”Ṣugbọn èyí ekeji dáhùn pé, “Rárá! Kò ní jẹ́ tèmi, kò sì ní jẹ́ tìrẹ. Jẹ́ kí wọ́n là á sí meji.”

27. Ọba dáhùn, ó ní, “Ẹ má pa ààyè ọmọ yìí rárá, ẹ gbé e fún obinrin àkọ́kọ́. Òun gan-an ni ìyá rẹ̀.”

28. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ irú ìdájọ́ tí Solomoni ọba dá yìí, ó mú kí ó túbọ̀ níyì lójú wọn; nítorí wọ́n mọ̀ pé Ọlọrun ni ó fún un ní ọgbọ́n láti ṣe ìdájọ́ ní irú ọ̀nà ẹ̀tọ́ bẹ́ẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 3