Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 22:43-49 BIBELI MIMỌ (BM)

43. Ohun tí ó dára lójú OLUWA, tí Asa baba rẹ̀ ṣe ni òun náà ṣe; ṣugbọn kò wó àwọn pẹpẹ ìrúbọ tí wọ́n wà káàkiri. Àwọn eniyan tún ń rúbọ, wọ́n sì tún ń sun turari níbẹ̀.

44. Jehoṣafati bá ọba Israẹli ṣọ̀rẹ́, alaafia sì wà láàrin wọn.

45. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoṣafati ṣe, gbogbo iṣẹ́ akikanju rẹ̀, ati gbogbo ogun tí ó jà, wà ninu àkọsílẹ̀ Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

46. Gbogbo àwọn aṣẹ́wó ọkunrin tí ó kù ní ilé àwọn oriṣa láti àkókò Asa, baba rẹ̀, ni ó parun ní ilẹ̀ náà.

47. Kò sí ọba ní ilẹ̀ Edomu. Adelé ọba kan ní ń ṣàkóso ilẹ̀ náà.

48. Jehoṣafati ọba kan àwọn ọkọ̀ ojú omi bíi ti ìlú Taṣiṣi, láti kó wọn lọ sí ilẹ̀ Ofiri láti lọ wá wúrà. Ṣugbọn wọn kò lè lọ nítorí pé àwọn ọkọ̀ náà bàjẹ́ ní Esiongeberi.

49. Ahasaya ọba Israẹli, ọmọ Ahabu, ọba Israẹli sọ fún Jehoṣafati pé kí àwọn eniyan òun bá àwọn eniyan rẹ̀ tu ọkọ̀ lọ, ṣugbọn Jehoṣafati kò gbà.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 22