Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 22:14-22 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Ṣugbọn Mikaaya dáhùn pé, “OLUWA alààyè, ń gbọ́! Ohun tí OLUWA bá wí fún mi ni n óo sọ.”

15. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ọba, ọba bi í pé, “Mikaaya, ṣé kí á lọ gbógun ti Ramoti Gileadi ni, àbí kí á má lọ?”Mikaaya dáhùn pé, “Lọ gbógun tì í, OLUWA yóo fún ọ ní ìṣẹ́gun.”

16. Ṣugbọn Ahabu tún bi í pé, “Ìgbà mélòó ni n óo sọ fún ọ pé, nígbà tí o bá sọ̀rọ̀ fún mi ní orúkọ OLUWA, kí o máa sọ òtítọ́ fún mi?”

17. Mikaaya bá dáhùn pé, “Mo rí àwọn ọmọ ogun Israẹli tí wọ́n fọ́n káàkiri gbogbo orí òkè, bí aguntan tí kò ní olùṣọ́. OLUWA sì wí pé, ‘Àwọn eniyan wọnyi kò ní olórí, kí olukuluku wọn pada lọ sí ilé ní alaafia.’ ”

18. Ahabu bá wí fún Jehoṣafati pé, “Ṣebí mo ti sọ fún ọ pé kì í sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi, àfi burúkú?”

19. Mikaaya dáhùn pé, “Ó dára, fetí sílẹ̀, kí o gbọ́ ohun tí OLUWA wí, mo rí i tí OLUWA jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run, gbogbo ogun ọ̀run sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ọ̀tún ati tòsì,

20. OLUWA bèèrè pé, ‘Ta ni yóo lọ tan Ahabu jẹ, kí ó lè lọ sí Ramoti Gileadi kí wọ́n sì pa á níbẹ̀?’ Bí angẹli kan ti ń sọ ọ̀kan bẹ́ẹ̀ ni òmíràn sì ń sọ nǹkan mìíràn.

21. Ẹ̀mí kan bá jáde siwaju OLUWA, ó ní, ‘N óo lọ tàn án jẹ.’

22. OLUWA bá bi í pé, ‘Ọgbọ́n wo ni o óo dá?’ Ẹ̀mí náà dáhùn pé, ‘N óo mú kí gbogbo àwọn wolii Ahabu purọ́ fún un.’ OLUWA bá dáhùn pé, ‘Lọ tàn án jẹ, o óo ṣe àṣeyọrí.’

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 22