Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 21:16-27 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Lẹsẹkẹsẹ bí Ahabu ti gbọ́ pé Naboti ti kú, ó lọ sí ibi ọgbà àjàrà náà, ó sì gbà á.

17. OLUWA bá sọ fún Elija wolii ará Tiṣibe pé,

18. “Lọ bá Ahabu, ọba Israẹli, tí ń gbé Samaria; o óo bá a ninu ọgbà àjàrà Naboti, tí ó lọ gbà.

19. Sọ pé, OLUWA ní kí o sọ fún un pé ṣé o ti pa ọkunrin yìí, o sì ti gba ọgbà àjàrà rẹ̀? Wí fún un pé, mo ní, ibi tí ajá ti lá ẹ̀jẹ̀ Naboti gan-an ni ajá yóo ti lá ẹ̀jẹ̀ tirẹ̀ náà.”

20. Nígbà tí Ahabu rí Elija, ó bi í pé, “O tún ti rí mi kọ́, ìwọ ọ̀tá mi?”Elija bá dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo tún ti rí ọ; nítorí pé o ti fa ara rẹ kalẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ burúkú níwájú OLUWA.

21. OLUWA ní òun óo jẹ́ kí ibi bá ọ, òun óo pa ọ́ rẹ́, òun ó sì run gbogbo ọkunrin tí ń bẹ ninu ìdílé rẹ, ati ẹrú ati ọmọ.

22. Ó ní bí òun ti ṣe ìdílé Jeroboamu, ọmọ Nebati, ati ti Baaṣa, ọmọ Ahija, bẹ́ẹ̀ ni òun óo ṣe ìdílé rẹ; nítorí o ti jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli dẹ́ṣẹ̀, o sì ti mú òun OLUWA bínú.

23. Ní ti Jesebẹli, OLUWA ní, ajá ni yóo jẹ òkú rẹ̀ láàrin ìlú Jesireeli.

24. Ẹni tí ó bá kú sí ààrin ìlú ninu ìdílé ìwọ Ahabu, ajá ni yóo jẹ òkú rẹ̀, ẹni tí ó bá sì kú sinu pápá, àwọn ẹyẹ ni yóo jẹ òkú rẹ̀.”

25. (Kò sí ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ burúkú lójú OLUWA gẹ́gẹ́ bíi Ahabu, tí Jesebẹli aya rẹ̀, ń tì gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n láti ṣe iṣẹ́ burúkú.

26. Gbogbo ọ̀nà ìríra tí àwọn ará Amori ń gbà bọ oriṣa ni Ahabu pàápàá ń gbà bọ oriṣa rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni lílé sì ni OLUWA lé àwọn ará Amori jáde kúrò ní ilẹ̀ Kenaani fún àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọn ń bọ̀.)

27. Nígbà tí Elija parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ahabu fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn, ó bọ́ wọn kúrò, ó sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀. Ó gbààwẹ̀, orí aṣọ ọ̀fọ̀ ni ó sì ń sùn; ó sì ń káàkiri pẹlu ìdoríkodò ati ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 21