Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 21:10-18 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Kí ẹ wá àwọn eniyankeniyan meji kan tí wọ́n ya aṣa, kí wọ́n jókòó níwájú rẹ̀, kí wọ́n sì fi ẹ̀sùn kàn án pé, ó bú Ọlọrun ati ọba. Lẹ́yìn náà, ẹ mú un jáde sẹ́yìn odi ìlú, kí ẹ sì sọ ọ́ lókùúta pa.”

11. Àwọn àgbààgbà ati àwọn eniyan ńláńlá tí wọn ń gbé ìlú náà ṣe bí Jesebẹli ti ní kí wọ́n ṣe ninu ìwé tí ó kọ ranṣẹ sí wọn.

12. Wọ́n kéde ọjọ́ ààwẹ̀ kan, wọ́n pe àwọn eniyan jọ, wọ́n sì fún Naboti ní ipò ọlá láàrin wọn.

13. Àwọn eniyankeniyan meji tí wọ́n ya aṣa yìí jókòó níwájú rẹ̀, wọ́n sì purọ́ mọ́ ọn lójú gbogbo eniyan pé ó bú Ọlọrun ati ọba. Wọ́n bá fà á jáde sẹ́yìn odi ìlú, wọ́n sì sọ ọ́ lókùúta pa.

14. Lẹ́yìn náà wọ́n ranṣẹ sí Jesebẹli pé àwọn ti sọ Naboti lókùúta pa.

15. Bí Jesebẹli ti gbọ́ pé wọ́n ti sọ Naboti lókùúta pa, ó sọ fún Ahabu pé, “Gbéra nisinsinyii, kí o sì lọ gba ọgbà àjàrà tí Naboti kọ̀ láti tà fún ọ, nítorí pé ó ti kú.”

16. Lẹsẹkẹsẹ bí Ahabu ti gbọ́ pé Naboti ti kú, ó lọ sí ibi ọgbà àjàrà náà, ó sì gbà á.

17. OLUWA bá sọ fún Elija wolii ará Tiṣibe pé,

18. “Lọ bá Ahabu, ọba Israẹli, tí ń gbé Samaria; o óo bá a ninu ọgbà àjàrà Naboti, tí ó lọ gbà.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 21