Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 20:10-25 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Benhadadi ọba tún ranṣẹ pada pé, “Àwọn oriṣa ń gbọ́! Mò ń kó àwọn eniyan bọ̀ láti pa ìlú Samaria run, wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jẹ́ pé ọwọ́ lásán ni wọn yóo fi kó gbogbo erùpẹ̀ ìlú náà. Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, kí àwọn oriṣa pa mí.”

11. Ahabu ọba ranṣẹ pada, ó ní, “Jagunjagun kan kì í fọ́nnu kí ó tó lọ sójú ogun, ó di ìgbà tí ó bá lọ sógun tí ó bá bọ̀.”

12. Nígbà tí Benhadadi gbọ́ iṣẹ́ yìí níbi tí ó ti ń mu ọtí pẹlu àwọn ọba yòókù ninu àgọ́, ó pàṣẹ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé kí wọ́n lọ múra ogun. Wọ́n bá múra láti bá Samaria jagun.

13. Wolii kan bá tọ Ahabu ọba lọ, ó wí fún un pé, “OLUWA ní kí n wí fún ọ pé, ‘Ṣé o rí gbogbo àwọn ọmọ ogun yìí bí wọ́n ti pọ̀ tó? Wò ó! N óo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí wọn lónìí, o óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ”

14. Ahabu bèèrè pé, “Ta ni yóo ṣáájú ogun?”Wolii náà dáhùn pé, “OLUWA ní, àwọn iranṣẹ gomina ìpínlẹ̀ ni.”Ahabu tún bèèrè pé, “Ta ni yóo bẹ̀rẹ̀ ogun náà?”Wolii náà dáhùn pé, “Ìwọ gan-an ni.”

15. Ọba bá pe gbogbo àwọn iranṣẹ tí wọ́n wà lábẹ́ àwọn gomina ìpínlẹ̀ jọ, gbogbo wọn jẹ́ ojilerugba ó dín mẹjọ (232), ó sì pe gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli jọ, gbogbo wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaarin (7,000).

16. Nígbà tí ó di ọ̀sán, wọ́n kó ogun jáde, bí Benhadadi ọba ati àwọn ọba mejilelọgbọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ti ń mu ọtí àmupara ninu àgọ́ wọn.

17. Àwọn ọ̀dọ́ ọmọ ogun ni wọ́n ṣáájú ogun Israẹli, wọ́n bá lọ ṣígun bá Benhadadi. Àwọn amí tí ọba Benhadadi rán jáde lọ ròyìn fún un pé, àwọn eniyan kan ń jáde bọ̀ láti ìlú Samaria.

18. Ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n mú wọn láàyè, wọ́n ìbáà máa bọ̀ wá jagun, wọn ìbáà sì máa bọ̀ wá sọ̀rọ̀ alaafia.

19. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ogun ṣe jáde ní ìlú: àwọn ọ̀dọ́ ọmọ ogun ni wọ́n ṣáájú ogun, lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ ogun Israẹli tẹ̀lé wọn.

20. Olukuluku wọn pa ẹni tí ó dojú ìjà kọ. Àwọn ọmọ ogun Siria bá sá. Àwọn ọmọ ogun Israẹli sì ń lé wọn lọ. Ṣugbọn Benhadadi, ọba Siria, ti gun ẹṣin sá lọ, pẹlu àwọn jagunjagun tí wọ́n gun ẹṣin.

21. Ahabu ọba bá lọ sójú ogun, ó kó ọpọlọpọ ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun; ó ṣẹgun àwọn ọmọ ogun Siria, ó sì pa ọpọlọpọ ninu wọn.

22. Wolii náà tún tọ Ahabu ọba lọ, ó wí fún un pé, “Pada lọ kó àwọn ọmọ ogun rẹ jọ, kí o sì ṣètò dáradára; nítorí pé, ọba Siria yóo tún bá ọ jagun ní ìbẹ̀rẹ̀ àkókò òjò.”

23. Àwọn oníṣẹ́ Benhadadi ọba wí fún un pé, “Oriṣa orí òkè ni oriṣa àwọn ọmọ Israẹli. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ṣẹgun wa. Ṣugbọn bí a bá gbógun tì wọ́n ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, a óo ṣẹgun wọn.

24. Nítorí náà, mú àwọn ọba mejeejilelọgbọn kúrò ní ààyè wọn gẹ́gẹ́ bí olórí ogun, kí o sì fi àwọn ọ̀gágun gidi dípò wọn.

25. Kí o wá kó àwọn ọmọ ogun mìíràn jọ, kí wọ́n pọ̀ bí i ti àkọ́kọ́, kí ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun pọ̀ bákan náà. A óo bá àwọn ọmọ Israẹli jagun ní pẹ̀tẹ́lẹ̀; láìsí àní àní, a óo sì ṣẹgun wọn.”Ọba Benhadadi gba ìmọ̀ràn wọn, ó sì ṣe ohun tí wọ́n wí.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 20