Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 20:1-15 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Benhadadi, ọba Siria kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ; àwọn ọba mejilelọgbọn ni wọ́n wá láti ràn án lọ́wọ́, pẹlu gbogbo ẹṣin, ati gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun wọn. Wọ́n dó ti ìlú Samaria, wọ́n sì bá a jagun.

2. Ó rán àwọn oníṣẹ́ sí ààrin ìlú pé kí wọ́n sọ fún Ahabu, ọba Israẹli pé, “Benhadadi ọba ní,

3. ‘Tèmi ni gbogbo fadaka ati wúrà rẹ, tèmi náà sì ni àwọn tí wọ́n dára jùlọ lára àwọn aya rẹ, ati àwọn ọmọ rẹ.’ ”

4. Ahabu ọba bá ranṣẹ pada pé, “Gẹ́gẹ́ bí o ti sọ, oluwa mi, ìwọ ni o ni mí ati gbogbo ohun tí mo ní.”

5. Àwọn oníṣẹ́ náà tún pada wá sí ọ̀dọ̀ Ahabu, wọ́n ní Benhadadi ọba tún ranṣẹ, ó ní, òun ti ranṣẹ sí Ahabu pé kí ó kó fadaka rẹ̀ ati wúrà rẹ̀, ati àwọn obinrin rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀ fún òun,

6. ṣugbọn òun óo rán àwọn oníṣẹ́ òun sí i ní ìwòyí ọ̀la láti yẹ ààfin rẹ̀ wò ati ilé àwọn oníṣẹ́ rẹ̀, kí wọ́n sì kó ohunkohun tí ó bá wù wọ́n.

7. Nígbà náà ni Ahabu ọba ranṣẹ pe gbogbo àwọn àgbààgbà ilẹ̀ náà, ó wí fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí i pé ọkunrin yìí ń wá ìjàngbọ̀n? Ó ranṣẹ wá pé kí n kó fadaka ati wúrà mi, ati àwọn obinrin mi, ati àwọn ọmọ mi fún òun, n kò sì bá a jiyàn.”

8. Àwọn àgbààgbà bá dá a lóhùn pé, “Má dá a lóhùn rárá, má sì gbà fún un.”

9. Ahabu bá ranṣẹ pada sí Benhadadi ọba pé, “Mo faramọ́ ohun tí ó kọ́kọ́ bèèrè fún, ṣugbọn n kò lè gba ti ẹẹkeji yìí.”Àwọn oníṣẹ́ náà pada lọ jíṣẹ́ fún Benhadadi ọba.

10. Benhadadi ọba tún ranṣẹ pada pé, “Àwọn oriṣa ń gbọ́! Mò ń kó àwọn eniyan bọ̀ láti pa ìlú Samaria run, wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jẹ́ pé ọwọ́ lásán ni wọn yóo fi kó gbogbo erùpẹ̀ ìlú náà. Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, kí àwọn oriṣa pa mí.”

11. Ahabu ọba ranṣẹ pada, ó ní, “Jagunjagun kan kì í fọ́nnu kí ó tó lọ sójú ogun, ó di ìgbà tí ó bá lọ sógun tí ó bá bọ̀.”

12. Nígbà tí Benhadadi gbọ́ iṣẹ́ yìí níbi tí ó ti ń mu ọtí pẹlu àwọn ọba yòókù ninu àgọ́, ó pàṣẹ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé kí wọ́n lọ múra ogun. Wọ́n bá múra láti bá Samaria jagun.

13. Wolii kan bá tọ Ahabu ọba lọ, ó wí fún un pé, “OLUWA ní kí n wí fún ọ pé, ‘Ṣé o rí gbogbo àwọn ọmọ ogun yìí bí wọ́n ti pọ̀ tó? Wò ó! N óo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí wọn lónìí, o óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ”

14. Ahabu bèèrè pé, “Ta ni yóo ṣáájú ogun?”Wolii náà dáhùn pé, “OLUWA ní, àwọn iranṣẹ gomina ìpínlẹ̀ ni.”Ahabu tún bèèrè pé, “Ta ni yóo bẹ̀rẹ̀ ogun náà?”Wolii náà dáhùn pé, “Ìwọ gan-an ni.”

15. Ọba bá pe gbogbo àwọn iranṣẹ tí wọ́n wà lábẹ́ àwọn gomina ìpínlẹ̀ jọ, gbogbo wọn jẹ́ ojilerugba ó dín mẹjọ (232), ó sì pe gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli jọ, gbogbo wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaarin (7,000).

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 20