Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 2:9-21 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ṣugbọn o kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó lọ láìjìyà. Ìwọ náà mọ ohun tí ó yẹ kí o ṣe gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n ọmọ, o kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó fi ọwọ́ rọrí kú.”

10. Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà, Dafidi, ọba kú, wọ́n sì sin ín sí ìlú Dafidi.

11. Ogoji ọdún ni ó fi jọba Israẹli. Ó ṣe ọdún meje lórí oyè ní Heburoni, ó sì ṣe ọdún mẹtalelọgbọn ní Jerusalẹmu.

12. Solomoni gorí oyè lẹ́yìn ikú baba rẹ̀, ìjọba rẹ̀ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọningbọnin.

13. Ní ọjọ́ kan, Adonija ọmọ Hagiti, lọ sí ọ̀dọ̀ Batiṣeba, ìyá Solomoni. Batiṣeba bá bèèrè pé, “Ṣé alaafia ni o?”Adonija dá a lóhùn pé, “Alaafia ni,

14. kinní kan ni mo fẹ́ bá ọ sọ.”Batiṣeba bi í pé, “Kí ni?”

15. Ó bá dá Batiṣeba lóhùn pé, “Ṣé o mọ̀ pé èmi ni ó yẹ kí n jọba, ati pé gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n lérò pé èmi ni n óo jọba. Ṣugbọn kò rí bẹ́ẹ̀, arakunrin mi ló jọba, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni ó wu OLUWA.

16. Kinní kan ni mo wá fẹ́ tọrọ, jọ̀wọ́, má fi kinní ọ̀hún dù mí.”Batiṣeba bá bi í pé, “Kí ni nǹkan náà?”

17. Ó bá dá Batiṣeba lóhùn, ó ní, “Jọ̀wọ́ bá mi bẹ Solomoni ọba, kí ó fún mi ní Abiṣagi, ará Ṣunemu, kí n fi ṣe aya. Mo mọ̀ pé kò ní kọ̀ sí ọ lẹ́nu.”

18. Batiṣeba bá dá a lóhùn pé, “Ó dára, n óo bá ọba sọ̀rọ̀.”

19. Batiṣeba bá lọ sọ́dọ̀ ọba láti jíṣẹ́ Adonija fún un. Bí ó ti wọlé, ọba dìde, ó tẹríba fún ìyá rẹ̀, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó bá tún jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀, ó ní kí wọ́n gbé ìjókòó kan wá, ìyá rẹ̀ sì jókòó ní apá ọ̀tún rẹ̀.

20. Batiṣeba wí fún Solomoni pé, “Nǹkan kékeré kan ni mo fẹ́ tọrọ lọ́wọ́ rẹ, jọ̀wọ́, má fi ohun náà dù mi.”Ọba bèèrè pé, “Kí ni, ìyá mi?” Ó sì fi kún un pé òun kò ní fi dù ú.

21. Batiṣeba dá a lóhùn pé, “Fi Abiṣagi, ará Ṣunemu fún Adonija arakunrin rẹ, kí ó fi ṣe aya.”

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 2