Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 2:28-46 BIBELI MIMỌ (BM)

28. Nígbà tí Joabu gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó sá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, ó sì di ìwo pẹpẹ mú, nítorí pé lẹ́yìn Adonija ni ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí lẹ́yìn Absalomu.

29. Nígbà tí Solomoni gbọ́ pé Joabu ti sá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, ati pé ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ, Solomoni rán Bẹnaya kí ó lọ pa á.

30. Bẹnaya bá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, ó wí fún Joabu pé, “Ọba pàṣẹ pé kí o jáde.”Ṣugbọn Joabu dá a lóhùn, ó ní, “Rárá, níhìn-ín ni n óo kú sí.”Bẹnaya bá pada lọ sọ ohun tí Joabu wí fún ọba.

31. Ọba dá a lóhùn pé, “Ṣe bí Joabu ti ní kí o ṣe. Pa á, kí o sì sin ín. Nígbà náà ni ọrùn èmi, ati arọmọdọmọ Dafidi yóo tó mọ́ kúrò ninu ohun tí Joabu ṣe nígbà tí ó pa àwọn aláìṣẹ̀.

32. OLUWA yóo jẹ Joabu níyà fún àwọn eniyan tí ó pa láìjẹ́ pé Dafidi baba mí mọ ohunkohun nípa rẹ̀. Ó pa Abineri, ọmọ Neri, ọ̀gágun àwọn ọmọ ogun Israẹli ati Amasa, ọmọ Jeteri, ọ̀gágun àwọn ọmọ ogun Juda. Àwọn mejeeji tí ó pa láìṣẹ̀ yìí ṣe olóòótọ́ ju òun pàápàá lọ.

33. Ẹ̀jẹ̀ àwọn tí ó pa yóo wà lórí rẹ̀ ati lórí àwọn arọmọdọmọ rẹ̀ títí lae, ṣugbọn OLUWA yóo fún Dafidi ati àwọn arọmọdọmọ rẹ̀ ati ilé rẹ̀ ati ìjọba rẹ̀ ní alaafia títí lae.”

34. Bẹnaya ọmọ Jehoiada bá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, ó pa Joabu, wọn sì sin ín sinu ilé rẹ̀ ninu aṣálẹ̀.

35. Ọba fi Bẹnaya jẹ balogun rẹ̀ dípò Joabu, ó sì fi Sadoku jẹ alufaa dípò Abiatari.

36. Lẹ́yìn náà, ọba ranṣẹ pe Ṣimei, ó wí fún un pé, “Kọ́ ilé kan sí Jerusalẹmu níhìn-ín kí o sì máa gbé ibẹ̀. O kò gbọdọ̀ jáde lọ sí ibìkankan.

37. Ọjọ́ tí o bá jáde kọjá odò Kidironi, pípa ni n óo pa ọ́, ẹ̀jẹ̀ rẹ yóo sì wà lórí ara rẹ.”

38. Ṣimei dá a lóhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tí o sọ ni ó dára, oluwa mi, bí o ti wí ni èmi iranṣẹ rẹ yóo sì ṣe.” Ṣimei sì wà ní Jerusalẹmu fún ìgbà pípẹ́.

39. Lẹ́yìn ọdún mẹta, àwọn ẹrú Ṣimei meji kan sá lọ sí ọ̀dọ̀ Akiṣi, ọmọ Maaka, ọba ìlú Gati. Nígbà tí Ṣimei gbọ́ pé àwọn ẹrú rẹ̀ yìí wà ní Gati,

40. ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ kan ní gàárì, ó sì tọ Akiṣi ọba lọ sí ìlú Gati láti lọ wá àwọn ẹrú rẹ̀. Ó rí wọn, ó sì mú àwọn mejeeji pada wá sí ilé.

41. Nígbà tí Solomoni gbọ́ pé Ṣimei ti kúrò ní Jerusalẹmu, ó ti lọ sí Gati, ó sì ti pada,

42. ó ranṣẹ pè é, ó bi í pé, “Ṣebí o búra fún mi ní orúkọ OLUWA pé o kò ní jáde kúrò ní Jerusalẹmu? Mo sì kìlọ̀ fún ọ pé, ní ọjọ́ tí o bá jáde, pípa ni n óo pa ọ́. O gbà bẹ́ẹ̀, o sì ṣèlérí fún mi pé o óo pa òfin náà mọ́.

43. Kí ló dé tí o kò mú ìlérí rẹ fún OLUWA ṣẹ, tí o sì rú òfin mi?”

44. Dájúdájú o mọ gbogbo ibi tí o ṣe sí Dafidi, baba mi; OLUWA yóo jẹ ọ́ níyà ohun tí o ṣe.

45. Ṣugbọn OLUWA yóo bukun mi, yóo sì fi ẹsẹ̀ ìjọba Dafidi múlẹ̀ títí lae.

46. Solomoni ọba bá pàṣẹ fún Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, pé kí ó lọ pa Ṣimei; Bẹnaya bá jáde lọ, ó sì pa á. Lẹ́yìn náà ni gbogbo ìjọba Solomoni ọba wá wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 2