Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 18:7-16 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Bí Ọbadaya ti ń lọ, lójijì ni ó pàdé Elija. Ó ranti rẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó sì bi í léèrè pé, “Àbí ìwọ kọ́ ni, Elija, oluwa mi?”

8. Elija dá a lóhùn pé, “Èmi ni, lọ sọ fún oluwa rẹ, ọba, pé èmi Elija wà níhìn-ín.”

9. Ọbadaya bá bèèrè pé, “Kí ni mo ṣe, tí o fi fẹ́ fa èmi iranṣẹ rẹ, lé Ahabu ọba lọ́wọ́ láti pa?

10. OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́, pé ọba ti wá ọ káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. Bí ọba ìlú kan, tabi tí orílẹ̀-èdè kan, bá sọ pé o kò sí ní ilẹ̀ òun, Ahabu á ní dandan, àfi kí wọ́n búra pé lóòótọ́ ni wọn kò rí ọ.

11. Nisinsinyii, o wá sọ fún mi pé kí n lọ sọ fún oluwa mi pé o wà níhìn-ín.

12. Bí mo bá kúrò lọ́dọ̀ rẹ tán tí ẹ̀mí Ọlọrun bá gbé ọ lọ sí ibi tí n kò mọ̀ ńkọ́? Bí mo bá lọ sọ fún Ahabu pé o wà níhìn-ín, tí kò bá rí ọ mọ́, pípa ni yóo pa mí; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ìgbà èwe mi ni mo ti bẹ̀rù OLUWA.

13. Àbí o kò gbọ́ nígbà tí Jesebẹli ń pa àwọn wolii OLUWA, pé mo kó ọgọrun-un ninu wọn pamọ́ sinu ihò àpáta meji, mo kó araadọta sinu ihò kọ̀ọ̀kan, mo sì ń fún wọn ní oúnjẹ ati omi.

14. O ṣe wá sọ pé kí n lọ sọ fún oluwa mi pé o wà níhìn-ín? Pípa ni yóo pa mí.”

15. Elija dá a lóhùn pé, “Ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun, tí mò ń sìn, mo ṣèlérí fún ọ pé, n óo fara han ọba lónìí.”

16. Ọbadaya bá lọ sọ fún ọba, ọba sì lọ pàdé Elija.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 18