Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 18:22-36 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Elija tún sọ fún wọn pé, “Èmi nìkan ṣoṣo ni wolii OLUWA tí ó ṣẹ́kù, ṣugbọn àwọn wolii oriṣa Baali tí wọ́n wà jẹ́ aadọtalenirinwo (450).

23. Ẹ fún wa ní akọ mààlúù meji, kí àwọn wolii Baali mú ọ̀kan, kí wọ́n pa á, kí wọ́n sì gé e kéékèèké. Kí wọ́n kó o sórí igi, ṣugbọn kí wọ́n má fi iná sí i. Èmi náà yóo pa akọ mààlúù keji, n óo kó o sórí igi, n kò sì ní fi iná sí i.

24. Lẹ́yìn náà, ẹ̀yin ẹ ké pe oriṣa Baali, Ọlọrun yín, èmi náà yóo sì ké pe OLUWA. Èyíkéyìí ninu wọn tí ó bá dáhùn, tí ó bá mú kí iná ṣẹ́, òun ni Ọlọrun.”Àwọn eniyan náà bá pariwo pé, “A gbà bẹ́ẹ̀.”

25. Elija bá sọ fún àwọn wolii Baali pé, “Ẹ̀yin ni ẹ pọ̀, ẹ̀yin ẹ kọ́kọ́ mú akọ mààlúù kan, kí ẹ tọ́jú rẹ̀. Ẹ gbadura sí oriṣa yín ṣugbọn ẹ má fi iná sí igi ẹbọ yín.”

26. Wọ́n mú akọ mààlúù tí wọ́n fún wọn, wọ́n pa á, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ké pe oriṣa Baali láti àárọ̀ títí di ọ̀sán. Wọ́n ń wí pé, “Baali, dá wa lóhùn!” Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò fọhùn. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jó yípo pẹpẹ tí wọ́n kọ́. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò dá wọn lóhùn.

27. Nígbà tí ó di ọ̀sán, Elija bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ pé, “Ẹ kígbe sókè, nítorí pé Ọlọrun ṣá ni. Bóyá ó ronú lọ ni, bóyá ó sì wọ ilé ìgbọ̀nsẹ̀ lọ ni; tabi ó lè jẹ́ pé ó lọ sí ìrìn àjò ni. Bóyá ó sùn ni, ẹ sì níláti jí i.”

28. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí kígbe sókè, wọ́n ń fi idà ati ọ̀kọ̀ ya ara wọn lára, gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, títí tí ẹ̀jẹ̀ fi bò wọ́n.

29. Nígbà tí ọ̀sán pọ́n, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kígbe, wọ́n ń sáré kiri bíi wèrè, títí tí ó fi di àkókò ìrúbọ ọ̀sán, ṣugbọn Baali kò dá wọn lóhùn rárá. Kò tilẹ̀ fọhùn.

30. Nígbà tó yá, Elija wí fún gbogbo àwọn eniyan náà pé, “Ẹ súnmọ́ mi níhìn-ín.” Gbogbo wọn súnmọ́ ọn, wọ́n sì yí i ká. Ó bá tún pẹpẹ OLUWA tí ó ti wó ṣe.

31. Ó kó òkúta mejila jọ, òkúta kọ̀ọ̀kan dúró fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Jakọbu, ẹni tí OLUWA sọ fún pé, “Israẹli ni orúkọ rẹ yóo máa jẹ́.”

32. Ó fi òkúta mejeejila náà kọ́ pẹpẹ ní orúkọ OLUWA. Ó gbẹ́ kòtò kan yí pẹpẹ náà ká, kòtò náà tóbi tó láti gba òṣùnwọ̀n irúgbìn meji (nǹkan bíi lita mẹrinla).

33. Lẹ́yìn náà, ó to igi sórí pẹpẹ, ó gé akọ mààlúù náà sí wẹ́wẹ́, ó sì tò wọ́n sórí igi. Ó ní kí wọ́n pọn ẹ̀kún ìkòkò omi ńlá mẹrin, kí wọ́n dà á sórí ẹbọ ati igi náà, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀.

34. Ó ní kí wọ́n tún da mẹrin mìíràn, wọ́n tún ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ní kí wọ́n tún ṣe bẹ́ẹ̀ lẹẹkẹta, wọ́n sì tún ṣe bẹ́ẹ̀.

35. Omi náà ṣàn sílẹ̀ yí pẹpẹ ká, ó sì kún kòtò tí wọ́n gbẹ́ yípo.

36. Nígbà tí ó di àkókò ìrúbọ ìrọ̀lẹ́, Elija súnmọ́ ibi pẹpẹ náà, ó sì gbadura pé, “OLUWA, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Israẹli, fi hàn lónìí pé ìwọ ni Ọlọrun Israẹli, ati pé iranṣẹ rẹ ni mí, ati pé gbogbo ohun tí mò ń ṣe yìí, pẹlu àṣẹ rẹ ni.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 18