Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 18:10-25 BIBELI MIMỌ (BM)

10. OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́, pé ọba ti wá ọ káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. Bí ọba ìlú kan, tabi tí orílẹ̀-èdè kan, bá sọ pé o kò sí ní ilẹ̀ òun, Ahabu á ní dandan, àfi kí wọ́n búra pé lóòótọ́ ni wọn kò rí ọ.

11. Nisinsinyii, o wá sọ fún mi pé kí n lọ sọ fún oluwa mi pé o wà níhìn-ín.

12. Bí mo bá kúrò lọ́dọ̀ rẹ tán tí ẹ̀mí Ọlọrun bá gbé ọ lọ sí ibi tí n kò mọ̀ ńkọ́? Bí mo bá lọ sọ fún Ahabu pé o wà níhìn-ín, tí kò bá rí ọ mọ́, pípa ni yóo pa mí; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ìgbà èwe mi ni mo ti bẹ̀rù OLUWA.

13. Àbí o kò gbọ́ nígbà tí Jesebẹli ń pa àwọn wolii OLUWA, pé mo kó ọgọrun-un ninu wọn pamọ́ sinu ihò àpáta meji, mo kó araadọta sinu ihò kọ̀ọ̀kan, mo sì ń fún wọn ní oúnjẹ ati omi.

14. O ṣe wá sọ pé kí n lọ sọ fún oluwa mi pé o wà níhìn-ín? Pípa ni yóo pa mí.”

15. Elija dá a lóhùn pé, “Ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun, tí mò ń sìn, mo ṣèlérí fún ọ pé, n óo fara han ọba lónìí.”

16. Ọbadaya bá lọ sọ fún ọba, ọba sì lọ pàdé Elija.

17. Nígbà tí Ahabu rí Elija, ó wí fún un pé, “Ojú rẹ nìyí ìwọ tí ò ń yọ Israẹli lẹ́nu!”

18. Elija dáhùn pé, “Èmi kọ́ ni mò ń yọ Israẹli lẹ́nu, ìwọ gan-an ni. Ìwọ ati ilé baba rẹ; nítorí ẹ ti kọ òfin OLUWA sílẹ̀, ẹ sì ń sin oriṣa Baali.

19. Nítorí náà, pàṣẹ pé kí wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, kí wọ́n pàdé mi ní orí òkè Kamẹli. Kí aadọtalenirinwo (450) àwọn wolii oriṣa Baali ati àwọn irinwo (400) wolii oriṣa Aṣera, tí ayaba Jesebẹli ń bọ náà bá wọn wá.”

20. Ahabu bá ranṣẹ pé gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ati àwọn wolii oriṣa Baali, pé kí wọ́n pàdé òun ní orí òkè Kamẹli.

21. Elija bá súnmọ́ gbogbo àwọn eniyan, ó wí fún wọn pé, “Yóo ti pẹ́ tó, tí ẹ óo fi máa ṣe iyèméjì? Bí ó bá jẹ́ pé OLUWA ni Ọlọrun, ẹ máa sìn ín. Bí ó bá sì jẹ́ pé oriṣa Baali ni ẹ máa bọ ọ́.” Ṣugbọn àwọn eniyan náà kò sọ ohunkohun.

22. Elija tún sọ fún wọn pé, “Èmi nìkan ṣoṣo ni wolii OLUWA tí ó ṣẹ́kù, ṣugbọn àwọn wolii oriṣa Baali tí wọ́n wà jẹ́ aadọtalenirinwo (450).

23. Ẹ fún wa ní akọ mààlúù meji, kí àwọn wolii Baali mú ọ̀kan, kí wọ́n pa á, kí wọ́n sì gé e kéékèèké. Kí wọ́n kó o sórí igi, ṣugbọn kí wọ́n má fi iná sí i. Èmi náà yóo pa akọ mààlúù keji, n óo kó o sórí igi, n kò sì ní fi iná sí i.

24. Lẹ́yìn náà, ẹ̀yin ẹ ké pe oriṣa Baali, Ọlọrun yín, èmi náà yóo sì ké pe OLUWA. Èyíkéyìí ninu wọn tí ó bá dáhùn, tí ó bá mú kí iná ṣẹ́, òun ni Ọlọrun.”Àwọn eniyan náà bá pariwo pé, “A gbà bẹ́ẹ̀.”

25. Elija bá sọ fún àwọn wolii Baali pé, “Ẹ̀yin ni ẹ pọ̀, ẹ̀yin ẹ kọ́kọ́ mú akọ mààlúù kan, kí ẹ tọ́jú rẹ̀. Ẹ gbadura sí oriṣa yín ṣugbọn ẹ má fi iná sí igi ẹbọ yín.”

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 18