Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 18:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, ní ọdún kẹta tí ọ̀dá ti dá, OLUWA sọ fún Elija pé, “Lọ fi ara rẹ han Ahabu ọba, n óo sì rọ̀jò sórí ilẹ̀.”

2. Elija bá lọ fi ara han Ahabu.Ìyàn tí ó mú ní ìlú Samaria pọ̀ pupọ.

3. Ahabu pe Ọbadaya, tí ó jẹ́ alabojuto ààfin. Ọbadaya jẹ́ ẹni tí ó bẹ̀rù OLUWA gan-an.

4. Nígbà tí Jesebẹli bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn wolii OLUWA, Ọbadaya yìí ló kó ọgọrun-un ninu wọn pamọ́ sinu ihò àpáta meji, ó kó aadọta sinu ihò kọ̀ọ̀kan, ó sì ń fún wọn ní oúnjẹ ati omi.

5. Ahabu sọ fún Ọbadaya pé, “Lọ wo gbogbo orísun omi ati àfonífojì ní gbogbo ilẹ̀ yìí, kí o wò ó bóyá a lè rí koríko láti fi bọ́ àwọn ẹṣin ati àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, kí wọ́n má baà kú.”

6. Wọ́n ṣe àdéhùn ibi tí olukuluku yóo lọ wò ní gbogbo ilẹ̀ náà, olukuluku sì gba ọ̀nà tirẹ̀ lọ. Ahabu ọba lọ sí apá kan, Ọbadaya sì lọ sí apá keji.

7. Bí Ọbadaya ti ń lọ, lójijì ni ó pàdé Elija. Ó ranti rẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó sì bi í léèrè pé, “Àbí ìwọ kọ́ ni, Elija, oluwa mi?”

8. Elija dá a lóhùn pé, “Èmi ni, lọ sọ fún oluwa rẹ, ọba, pé èmi Elija wà níhìn-ín.”

9. Ọbadaya bá bèèrè pé, “Kí ni mo ṣe, tí o fi fẹ́ fa èmi iranṣẹ rẹ, lé Ahabu ọba lọ́wọ́ láti pa?

10. OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́, pé ọba ti wá ọ káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. Bí ọba ìlú kan, tabi tí orílẹ̀-èdè kan, bá sọ pé o kò sí ní ilẹ̀ òun, Ahabu á ní dandan, àfi kí wọ́n búra pé lóòótọ́ ni wọn kò rí ọ.

11. Nisinsinyii, o wá sọ fún mi pé kí n lọ sọ fún oluwa mi pé o wà níhìn-ín.

12. Bí mo bá kúrò lọ́dọ̀ rẹ tán tí ẹ̀mí Ọlọrun bá gbé ọ lọ sí ibi tí n kò mọ̀ ńkọ́? Bí mo bá lọ sọ fún Ahabu pé o wà níhìn-ín, tí kò bá rí ọ mọ́, pípa ni yóo pa mí; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ìgbà èwe mi ni mo ti bẹ̀rù OLUWA.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 18