Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 17:11-21 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Bí ó ti ń lọ bu omi náà, Elija tún pè é pada, ó ní, “Jọ̀wọ́ bá mi mú oúnjẹ díẹ̀ lọ́wọ́ sí i.”

12. Obinrin náà dáhùn pé, “OLUWA Ọlọrun rẹ ń gbọ́, n kò ní oúnjẹ rárá. Gbogbo ohun tí mo ní kò ju ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun kan lọ, tí ó wà ninu àwokòtò kan; ati ìwọ̀nba òróró olifi díẹ̀, ninu kólòbó kan. Igi ìdáná díẹ̀ ni mò ń wá níhìn-ín, kí n fi se ìwọ̀nba oúnjẹ díẹ̀ tí ó kù, fún èmi ati ọmọ mi; pé kí a jẹ ẹ́, kí a sì máa dúró de ọjọ́ ikú.”

13. Elija wí fún un pé, “Má bẹ̀rù. Lọ se oúnjẹ tí o fẹ́ sè, ṣugbọn kọ́kọ́ tọ́jú díẹ̀ lára rẹ̀, kí o sì gbé e wá fún mi. Lẹ́yìn náà, kí o lọ sè fún ara rẹ ati fún ọmọ rẹ.

14. Nítorí ohun tí OLUWA Ọlọrun Israẹli wí ni pé, ìyẹ̀fun kò ní tán ninu ìkòkò rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kólòbó òróró rẹ kò ní gbẹ títí tí OLUWA yóo fi rọ òjò sórí ilẹ̀.”

15. Obinrin yìí bá lọ, ó ṣe bí Elija ti wí. Òun ati Elija ati gbogbo ará ilé rẹ̀ sì ń jẹ àjẹyó fún ọpọlọpọ ọjọ́.

16. Ìyẹ̀fun kò tán ninu ìkòkò rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kólòbó òróró rẹ̀ kò sì gbẹ, bí OLUWA ti ṣèlérí fún un láti ẹnu Elija.

17. Lẹ́yìn èyí, ọmọ obinrin opó yìí ṣàìsàn. Àìsàn náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ọmọ náà ṣàìsí.

18. Obinrin náà bá bi Elija pé, “Eniyan Ọlọrun, kí ló dé tí o fi ṣe mí báyìí? Ṣé o wá sọ́dọ̀ mi láti rán Ọlọrun létí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi, ati láti ṣe ikú pa ọmọ mi ni.”

19. Elija dáhùn pé, “Gbé ọmọ náà fún mi.” Ó bá gba òkú ọmọ náà lọ́wọ́ rẹ̀, ó gbé e gun orí òkè ilé lọ sinu yàrá tí ó ń gbé, ó sì tẹ́ ẹ sórí ibùsùn rẹ̀.

20. Ó képe OLUWA, ó ní, “OLUWA, Ọlọrun mi, kí ló dé tí o fi jẹ́ kí irú ìdààmú yìí bá obinrin opó tí mò ń gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀ yìí, tí o jẹ́ kí ọmọ rẹ̀ kú?”

21. Elija bá na ara rẹ̀ sórí ọmọ yìí nígbà mẹta, ó sì ké pe OLÚWA, ó ní, “OLUWA Ọlọrun mi, jẹ́ kí ẹ̀mí ọmọ yìí tún pada sinu rẹ̀.”

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 17