Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 17:1-14 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Wolii kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elija, ará Tiṣibe, ní Gileadi, sọ fún Ahabu pé, “Bí OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí mò ń sìn ti wà láàyè, mò ń sọ fún ọ pé, òjò kò ní rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìrì kò ní sẹ̀ fún ọdún mélòó kan, àfi ìgbà tí mo bá sọ pé, kí òjò rọ̀, tabi kí ìrì sẹ̀.”

2. Lẹ́yìn náà, OLUWA sọ fún Elija pé,

3. “Kúrò níhìn-ín, kí o doríkọ apá ìhà ìlà oòrùn, kí o sì fi ara pamọ́ lẹ́bàá odò Keriti, tí ó wà ní apá ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani.

4. Ninu odò yìí ni o óo ti máa bu omi mu, mo sì ti pàṣẹ fún àwọn ẹyẹ ìwò kan pé kí wọ́n máa gbé oúnjẹ wá fún ọ níbẹ̀.”

5. Elija bá lọ, ó ṣe bí OLUWA ti wí, ó sì ń gbé ẹ̀bá odò Keriti, ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani.

6. Àwọn ẹyẹ ìwò ń gbé oúnjẹ ati ẹran wá fún un ní ojoojumọ, ní àràárọ̀ ati ní ìrọ̀lẹ́ ìrọ̀lẹ́, ó sì ń mu omi odò náà.

7. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, odò náà gbẹ nítorí àìrọ̀ òjò ní ilẹ̀ náà.

8. OLUWA bá tún sọ fún Elija pé,

9. “Dìde nisinsinyii, kí o lọ sí ìlú Sarefati, ní agbègbè Sidoni, kí o sì máa gbé ibẹ̀. Mo ti pàṣẹ fún opó kan níbẹ̀ láti máa fún ọ ní oúnjẹ.”

10. Elija bá lọ sí Sarefati. Bí ó ti dé ẹnu ọ̀nà ibodè ìlú náà, ó rí obinrin opó kan tí ń wá igi ìdáná. Ó wí fún obinrin yìí pé, “Jọ̀wọ́ lọ bá mi bu omi wá kí n mu.”

11. Bí ó ti ń lọ bu omi náà, Elija tún pè é pada, ó ní, “Jọ̀wọ́ bá mi mú oúnjẹ díẹ̀ lọ́wọ́ sí i.”

12. Obinrin náà dáhùn pé, “OLUWA Ọlọrun rẹ ń gbọ́, n kò ní oúnjẹ rárá. Gbogbo ohun tí mo ní kò ju ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun kan lọ, tí ó wà ninu àwokòtò kan; ati ìwọ̀nba òróró olifi díẹ̀, ninu kólòbó kan. Igi ìdáná díẹ̀ ni mò ń wá níhìn-ín, kí n fi se ìwọ̀nba oúnjẹ díẹ̀ tí ó kù, fún èmi ati ọmọ mi; pé kí a jẹ ẹ́, kí a sì máa dúró de ọjọ́ ikú.”

13. Elija wí fún un pé, “Má bẹ̀rù. Lọ se oúnjẹ tí o fẹ́ sè, ṣugbọn kọ́kọ́ tọ́jú díẹ̀ lára rẹ̀, kí o sì gbé e wá fún mi. Lẹ́yìn náà, kí o lọ sè fún ara rẹ ati fún ọmọ rẹ.

14. Nítorí ohun tí OLUWA Ọlọrun Israẹli wí ni pé, ìyẹ̀fun kò ní tán ninu ìkòkò rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kólòbó òróró rẹ kò ní gbẹ títí tí OLUWA yóo fi rọ òjò sórí ilẹ̀.”

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 17