Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 16:2-8 BIBELI MIMỌ (BM)

2. “O kò jámọ́ nǹkankan tẹ́lẹ̀, kí n tó fi ọ́ ṣe olórí àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi. Ṣugbọn irú ìgbésẹ̀ tí Jeroboamu gbé ni ìwọ náà gbé, ìwọ náà mú kí àwọn eniyan mi dẹ́ṣẹ̀; ẹ̀ṣẹ̀ wọn sì ti mú mi bínú gidigidi.

3. Nítorí náà, n óo pa ìwọ ati ìdílé rẹ rẹ́. Bí mo ti ṣe ìdílé Jeroboamu, bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe ìdílé tìrẹ náà.

4. Ẹnikẹ́ni ninu ìdílé rẹ tí ó bá kú láàrin ìlú, ajá ni yóo jẹ òkú rẹ̀, èyíkéyìí ninu wọn tí ó bá sì kú sinu igbó, àwọn ẹyẹ ni yóo jẹ òkú rẹ̀.”

5. Gbogbo nǹkan yòókù tí Baaṣa ṣe, ati gbogbo iṣẹ́ akikanju rẹ̀, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

6. Baaṣa kú, wọ́n sì sin ín sí Tirisa. Ela ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè lẹ́yìn rẹ̀.

7. Lẹ́yìn náà OLUWA ti ẹnu wolii Jehu ọmọ Hanani bá Baaṣa ati ìdílé rẹ̀ wí nítorí gbogbo ibi tí ó ṣe lójú OLUWA, tí ó fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ mú OLUWA bínú nítorí pé ó dẹ́ṣẹ̀ bíi Jeroboamu, ati pé òun ló tún pa ìdílé Jeroboamu run.

8. Ní ọdún kẹrindinlọgbọn tí Asa jọba ní Juda, ni Ela, ọmọ Baaṣa, gorí oyè ní ilẹ̀ Israẹli; ó sì jọba ní Tirisa fún ọdún meji.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 16