1. Ọlọrun rán wolii Jehu, ọmọ Hanani, pé kí ó sọ fún Baaṣa ọba pé,
2. “O kò jámọ́ nǹkankan tẹ́lẹ̀, kí n tó fi ọ́ ṣe olórí àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi. Ṣugbọn irú ìgbésẹ̀ tí Jeroboamu gbé ni ìwọ náà gbé, ìwọ náà mú kí àwọn eniyan mi dẹ́ṣẹ̀; ẹ̀ṣẹ̀ wọn sì ti mú mi bínú gidigidi.