Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 15:25-34 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Ní ọdún keji tí Asa jọba ní Juda, ni Nadabu, ọmọ Jeroboamu, gorí oyè ní ilẹ̀ Israẹli, ó sì jọba fún ọdún meji.

26. Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ọ̀nà baba rẹ̀, ó sì dá irú ẹ̀ṣẹ̀ tí baba rẹ̀ mú kí Israẹli dá.

27. Baaṣa, ọmọ Ahija, láti inú ẹ̀yà Isakari, ṣọ̀tẹ̀ sí Nadabu, ó sì pa á ní ìlú Gibetoni, ní ilẹ̀ Filistia, nígbà tí Nadabu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti ìlú náà.

28. Ní ọdún kẹta tí Asa gorí oyè ní ilẹ̀ Juda, ni Baaṣa pa Nadabu. Baaṣa gorí oyè dípò Nadabu, ó sì di ọba ilẹ̀ Israẹli.

29. Lẹsẹkẹsẹ tí Baaṣa gorí oyè ni ó bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo ìdílé Jeroboamu. Gbogbo ìran Jeroboamu pátá ni Baaṣa pa láìku ẹyọ ẹnìkan, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti sọ láti ẹnu iranṣẹ rẹ̀, wolii Ahija, ará Ṣilo.

30. Nítorí Jeroboamu ṣe ohun tí ó bí OLUWA Ọlọrun Israẹli ninu: ó dẹ́ṣẹ̀, ó sì mú kí Israẹli náà dẹ́ṣẹ̀.

31. Gbogbo nǹkan yòókù tí Nadabu ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

32. Ní gbogbo àsìkò tí Asa ọba Juda ati Baaṣa ọba Israẹli wà lórí oyè, ogun ni wọ́n ń bá ara wọn jà.

33. Ní ọdún kẹta tí Asa, ọba Juda, gorí oyè, ni Baaṣa, ọmọ Ahija, gorí oyè, ní ìlú Tirisa, ó sì di ọba gbogbo Israẹli. Ó jọba fún ọdún mẹrinlelogun.

34. Ó ṣe nǹkan tó burú lójú OLUWA, ó rìn ní ọ̀nà Jeroboamu, ó sì dá ẹ̀ṣẹ̀ tí Jeroboamu mú kí Israẹli dá.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 15