Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 15:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọdún kejidinlogun tí Jeroboamu jọba Israẹli, ni Abijamu gorí oyè ní ilẹ̀ Juda.

2. Ọdún mẹta ló fi jọba ní Jerusalẹmu. Maaka ọmọ Absalomu ni ìyá rẹ̀.

3. Gbogbo irú ẹ̀ṣẹ̀ tí baba Abijamu dá, ni òun náà dá. Kò fi tọkàntọkàn ṣe olóòótọ́ sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀ bí Dafidi, baba ńlá rẹ̀ ti ṣe.

4. Sibẹsibẹ, nítorí ti Dafidi, OLUWA Ọlọrun fún Abijamu ní ọmọkunrin kan tí ó gorí oyè lẹ́yìn rẹ̀, ní Jerusalẹmu, tí ó sì dáàbò bo Jerusalẹmu.

5. Ìdí rẹ̀ ni pé, Dafidi ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, kò sì ṣàìgbọràn sí àṣẹ rẹ̀ rí ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, (àfi ohun tí ó ṣe sí Uraya ará Hiti).

6. Ogun tí ó wà láàrin Rehoboamu ati Jeroboamu tún wà bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí Abijamu wà lórí oyè.

7. Gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Abijamu ṣe wà ninu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. Ogun si wà láàrin Abijah ati Jeroboamu.

8. Abijamu jáde láyé, wọ́n sì sin ín ní ìlú Dafidi, Asa, ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè lẹ́yìn rẹ̀.

9. Nígbà tí ó di ogún ọdún tí Jeroboamu ti jọba Israẹli ni Asa gorí oyè ní ilẹ̀ Juda.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 15