Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 14:3-11 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Mú burẹdi mẹ́wàá, àkàrà dídùn díẹ̀, ati ìgò oyin kan lọ́wọ́ fún un, yóo sì sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà fún ọ.”

4. Aya Jeroboamu sì ṣe bí Jeroboamu ti wí. Ó lọ sí ilé wolii Ahija ní Ṣilo. Ogbó ti dé sí Ahija ní àkókò yìí, kò sì ríran mọ́,

5. ṣugbọn OLUWA ti sọ fún un pé aya Jeroboamu ń bọ̀ wá bèèrè ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ọmọ rẹ̀ tí ó ń ṣàìsàn, OLUWA sì ti sọ ohun tí Ahija yóo sọ fún un.Nígbà tí aya Jeroboamu dé, ó ṣe bí ẹni pé ẹlòmíràn ni.

6. Ṣugbọn bí Ahija ti gbúròó rẹ̀ tí ó ń wọlé bọ̀ ní ẹnu ọ̀nà, ó ní, “Wọlé, ìwọ aya Jeroboamu. Kí ló dé tí o fi ń ṣe bí ẹni pé ẹlòmíràn ni ọ́? Ìròyìn burúkú ni mo ní fún ọ.

7. Lọ sọ fún Jeroboamu pé, ‘OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, “Mo gbé ọ ga láàrin àwọn eniyan náà, mo sì fi ọ́ jọba lórí Israẹli, àwọn eniyan mi.

8. Mo gba ìjọba lọ́wọ́ ìdílé Dafidi, mo sì fún ọ, o kò ṣe bíi Dafidi, iranṣẹ mi, tí ó pa òfin mi mọ́, tí ó sìn mí tọkàntọkàn, tí ó sì ṣe kìkì ohun tí ó dára lójú mi.

9. Ṣugbọn o ti dá ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ burúkú ju ti àwọn tí wọ́n jọba ṣáájú rẹ lọ. O yá ère, o sì dá oniruuru oriṣa láti máa sìn, o mú mi bínú, o sì ti pada lẹ́yìn mi.

10. Nítorí náà, n óo jẹ́ kí ibi bá ìdílé rẹ, n óo sì pa gbogbo ọkunrin inú ìdílé rẹ run, àtẹrú àtọmọ. Bí ìgbà tí eniyan bá sun pàǹtí, tí ó sì jóná ráúráú ni n óo pa gbogbo ìdílé rẹ run.

11. Ajá ni yóo jẹ òkú ẹnikẹ́ni ninu ìdílé rẹ tí ó bá kú láàrin ìlú; ẹni tí ó bá sì kú sinu igbó, ẹyẹ ni yóo jẹ òkú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA wí.” ’

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 14