Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 14:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní àkókò yìí Abija, ọmọ Jeroboamu ọba ṣàìsàn,

2. Jeroboamu wí fún aya rẹ̀ pé, “Dìde, kí o yíra pada, kí ẹnikẹ́ni má lè dá ọ mọ̀ pé aya ọba ni ọ́. Lọ sí Ṣilo níbi tí wolii Ahija tí ó wí fún mi pé n óo jọba Israẹli, ń gbé.

3. Mú burẹdi mẹ́wàá, àkàrà dídùn díẹ̀, ati ìgò oyin kan lọ́wọ́ fún un, yóo sì sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà fún ọ.”

4. Aya Jeroboamu sì ṣe bí Jeroboamu ti wí. Ó lọ sí ilé wolii Ahija ní Ṣilo. Ogbó ti dé sí Ahija ní àkókò yìí, kò sì ríran mọ́,

5. ṣugbọn OLUWA ti sọ fún un pé aya Jeroboamu ń bọ̀ wá bèèrè ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ọmọ rẹ̀ tí ó ń ṣàìsàn, OLUWA sì ti sọ ohun tí Ahija yóo sọ fún un.Nígbà tí aya Jeroboamu dé, ó ṣe bí ẹni pé ẹlòmíràn ni.

6. Ṣugbọn bí Ahija ti gbúròó rẹ̀ tí ó ń wọlé bọ̀ ní ẹnu ọ̀nà, ó ní, “Wọlé, ìwọ aya Jeroboamu. Kí ló dé tí o fi ń ṣe bí ẹni pé ẹlòmíràn ni ọ́? Ìròyìn burúkú ni mo ní fún ọ.

7. Lọ sọ fún Jeroboamu pé, ‘OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, “Mo gbé ọ ga láàrin àwọn eniyan náà, mo sì fi ọ́ jọba lórí Israẹli, àwọn eniyan mi.

8. Mo gba ìjọba lọ́wọ́ ìdílé Dafidi, mo sì fún ọ, o kò ṣe bíi Dafidi, iranṣẹ mi, tí ó pa òfin mi mọ́, tí ó sìn mí tọkàntọkàn, tí ó sì ṣe kìkì ohun tí ó dára lójú mi.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 14