Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 13:9-24 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Nítorí pé, OLUWA ti pàṣẹ fún mi pé n kò gbọdọ̀ fẹnu kan nǹkankan ati pé, n kò gbọdọ̀ gba ọ̀nà tí mo gbà wá pada.”

10. Nítorí náà, kò gba ọ̀nà ibi tí ó gbà wá pada, ọ̀nà ibòmíràn ni ó gbà lọ.

11. Wolii àgbàlagbà kan wà ní ìlú Bẹtẹli ní ìgbà náà. Àwọn ọmọ wolii náà lọ sọ ohun tí wolii tí ó wá láti Juda ṣe ní Bẹtẹli ní ọjọ́ náà fún baba wọn, ati ohun tí ó sọ fún Jeroboamu ọba.

12. Wolii àgbàlagbà náà bá bi wọ́n pé, “Ọ̀nà ibo ni ó gbà lọ?” Wọ́n sì fi ọ̀nà náà hàn án.

13. Ó sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé kí wọ́n di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ òun ní gàárì, wọ́n di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì. Ó bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gùn,

14. ó bẹ̀rẹ̀ sí lépa wolii ará Juda náà. Ó bá a níbi tí ó jókòó sí lábẹ́ igi Oaku kan, ó bi í pé, ṣe òun ni wolii tí ó wá láti Juda? Ọkunrin náà sì dá a lóhùn pé òun ni.

15. Wolii àgbàlagbà yìí bá wí fún un pé, “Bá mi kálọ sílé, kí o lọ jẹun.”

16. Ṣugbọn wolii ará Juda náà dáhùn pé, “N kò gbọdọ̀ bá ọ pada lọ sí ilé rẹ, bẹ́ẹ̀ ni n kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan nǹkankan ní ilẹ̀ yìí.

17. Nítorí OLUWA ti pàṣẹ fún mi pé, n kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan ohunkohun; ati pé, ọ̀nà tí mo bá gbà wá síbí, n kò gbọdọ̀ gbà á pada lọ sílé.”

18. Wolii àgbàlagbà, ará Bẹtẹli náà bá purọ́ fún un pé, “Wolii bíi rẹ ni èmi náà. OLUWA ni ó sì pàṣẹ fún angẹli kan tí ó sọ fún mi pé kí n mú ọ lọ sí ilé, kí n sì fún ọ ní oúnjẹ ati omi.”

19. Wolii ará Juda yìí bá bá wolii àgbàlagbà náà pada lọ sí ilé rẹ̀, ó sì jẹun níbẹ̀.

20. Bí wọ́n ti jóòkó tí wọn ń jẹun, OLUWA bá wolii àgbàlagbà tí ó pè é pada sọ̀rọ̀.

21. Ó bá kígbe mọ́ wolii ará Juda yìí, ó ní, “OLUWA ní, nítorí pé o ti ṣe àìgbọràn sí òun, o kò sì ṣe ohun tí òun OLUWA Ọlọrun rẹ pa láṣẹ fún ọ.

22. Kàkà bẹ́ẹ̀, o pada, o jẹ, o sì mu ní ibi tí òun ti pàṣẹ pé o kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan nǹkankan. Nítorí náà, o óo kú, wọn kò sì ní sin òkú rẹ sinu ibojì àwọn baba rẹ.”

23. Nígbà tí wọ́n jẹun tan, wolii àgbàlagbà yìí di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan ní gàárì fún wolii ará Juda.

24. Wolii ará Juda náà bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gùn, ó ń lọ. Bí ó ti ń lọ lójú ọ̀nà, kinniun kan yọ sí i, ó sì pa á. Òkú rẹ̀ wà ní ojú ọ̀nà níbẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati kinniun náà sì dúró tì í.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 13