Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 13:7-22 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ọba bá sọ fún wolii náà pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ilé mi kí o lọ jẹun, n óo sì fún ọ ní ẹ̀bùn fún ohun tí o ṣe fún mi.”

8. Ṣugbọn wolii náà dáhùn pé, “Bí o bá tilẹ̀ fẹ́ fún mi ní ìdajì ohun tí o ní, n kò ní bá ọ lọ, n kò ní fi ẹnu kan nǹkankan ní ilẹ̀ yìí.

9. Nítorí pé, OLUWA ti pàṣẹ fún mi pé n kò gbọdọ̀ fẹnu kan nǹkankan ati pé, n kò gbọdọ̀ gba ọ̀nà tí mo gbà wá pada.”

10. Nítorí náà, kò gba ọ̀nà ibi tí ó gbà wá pada, ọ̀nà ibòmíràn ni ó gbà lọ.

11. Wolii àgbàlagbà kan wà ní ìlú Bẹtẹli ní ìgbà náà. Àwọn ọmọ wolii náà lọ sọ ohun tí wolii tí ó wá láti Juda ṣe ní Bẹtẹli ní ọjọ́ náà fún baba wọn, ati ohun tí ó sọ fún Jeroboamu ọba.

12. Wolii àgbàlagbà náà bá bi wọ́n pé, “Ọ̀nà ibo ni ó gbà lọ?” Wọ́n sì fi ọ̀nà náà hàn án.

13. Ó sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé kí wọ́n di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ òun ní gàárì, wọ́n di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì. Ó bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gùn,

14. ó bẹ̀rẹ̀ sí lépa wolii ará Juda náà. Ó bá a níbi tí ó jókòó sí lábẹ́ igi Oaku kan, ó bi í pé, ṣe òun ni wolii tí ó wá láti Juda? Ọkunrin náà sì dá a lóhùn pé òun ni.

15. Wolii àgbàlagbà yìí bá wí fún un pé, “Bá mi kálọ sílé, kí o lọ jẹun.”

16. Ṣugbọn wolii ará Juda náà dáhùn pé, “N kò gbọdọ̀ bá ọ pada lọ sí ilé rẹ, bẹ́ẹ̀ ni n kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan nǹkankan ní ilẹ̀ yìí.

17. Nítorí OLUWA ti pàṣẹ fún mi pé, n kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan ohunkohun; ati pé, ọ̀nà tí mo bá gbà wá síbí, n kò gbọdọ̀ gbà á pada lọ sílé.”

18. Wolii àgbàlagbà, ará Bẹtẹli náà bá purọ́ fún un pé, “Wolii bíi rẹ ni èmi náà. OLUWA ni ó sì pàṣẹ fún angẹli kan tí ó sọ fún mi pé kí n mú ọ lọ sí ilé, kí n sì fún ọ ní oúnjẹ ati omi.”

19. Wolii ará Juda yìí bá bá wolii àgbàlagbà náà pada lọ sí ilé rẹ̀, ó sì jẹun níbẹ̀.

20. Bí wọ́n ti jóòkó tí wọn ń jẹun, OLUWA bá wolii àgbàlagbà tí ó pè é pada sọ̀rọ̀.

21. Ó bá kígbe mọ́ wolii ará Juda yìí, ó ní, “OLUWA ní, nítorí pé o ti ṣe àìgbọràn sí òun, o kò sì ṣe ohun tí òun OLUWA Ọlọrun rẹ pa láṣẹ fún ọ.

22. Kàkà bẹ́ẹ̀, o pada, o jẹ, o sì mu ní ibi tí òun ti pàṣẹ pé o kò gbọdọ̀ fi ẹnu kan nǹkankan. Nítorí náà, o óo kú, wọn kò sì ní sin òkú rẹ sinu ibojì àwọn baba rẹ.”

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 13