Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 13:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA pàṣẹ fún wolii kan, ará Juda, pé kí ó lọ sí Bẹtẹli; nígbà tí ó débẹ̀ ó bá Jeroboamu tí ó dúró níwájú pẹpẹ láti sun turari.

2. Wolii náà bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ sí pẹpẹ náà, ó ní, “Ìwọ pẹpẹ yìí, ìwọ pẹpẹ yìí, gbọ́ ohun tí OLUWA wí, ó ní, ‘Wò ó! A óo bí ọmọ kan ninu ìdílé Dafidi, orúkọ rẹ̀ yóo máa jẹ́ Josaya. Lórí ìwọ pẹpẹ yìí ni yóo ti fi àwọn alufaa oriṣa tí ń sun turari lórí rẹ rúbọ. A óo sì máa sun egungun eniyan lórí rẹ.’ ”

3. Ó sì fún wọn ní àmì kan ní ọjọ́ náà, tí wọn yóo fi mọ̀ pé OLUWA ni ó gba ẹnu òun sọ̀rọ̀. Ó ní, “Pẹpẹ yìí yóo wó lulẹ̀, eérú orí rẹ̀ yóo sì fọ́n dànù.”

4. Nígbà tí Jeroboamu gbọ́ ìkìlọ̀ tí wolii Ọlọrun yìí ṣe fún pẹpẹ náà, ó na ọwọ́ sí wolii náà láti ibi pẹpẹ, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú un. Lẹsẹkẹsẹ, ọwọ́ ọba bá gan, kò sì lè gbé e wálẹ̀ mọ́.

5. Pẹpẹ náà wó lulẹ̀, eérú orí rẹ̀ sì fọ́n dànù gẹ́gẹ́ bí wolii náà ti sọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ OLUWA.

6. Jeroboamu ọba bẹ wolii náà pé, “Jọ̀wọ́, bẹ OLUWA Ọlọrun rẹ, kí o sì gbadura sí i pé kí ó wo apá mi sàn.”Wolii náà bá gbadura sí OLUWA, apá Jeroboamu ọba sì sàn, ó pada sí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀.

7. Ọba bá sọ fún wolii náà pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ilé mi kí o lọ jẹun, n óo sì fún ọ ní ẹ̀bùn fún ohun tí o ṣe fún mi.”

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 13