Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 12:21-33 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Nígbà tí Rehoboamu pada dé Jerusalẹmu, ó ṣa ọ̀kẹ́ mẹsan-an (180,000) ọmọ ogun tí wọ́n jẹ́ akikanju jùlọ láti inú ẹ̀yà Juda ati ti Bẹnjamini, láti lọ gbógun ti ilé Israẹli kí wọ́n sì gba ìjọba ìhà àríwá Israẹli pada fún un.

22. Ṣugbọn Ọlọrun sọ fún wolii Ṣemaaya,

23. pé kí ó jíṣẹ́ fún Rehoboamu, ọba Juda ati gbogbo ẹ̀yà Juda ati ti Bẹnjamini,

24. pé OLUWA ni wọn kò gbọdọ̀ gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli, nítorí pé arakunrin wọn ni wọ́n, ati pé kí olukuluku pada sí ilé rẹ̀, nítorí pé ìfẹ́ òun Ọlọrun ni ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ yìí. Nítorí náà gbogbo wọ́n gba ohun tí OLUWA pa láṣẹ, wọ́n sì pada sí ilé wọn bí OLUWA ti wí.

25. Jeroboamu ọba Israẹli mọ odi yí ìlú Ṣekemu, tí ó wà ní agbègbè olókè ti Efuraimu ká, ó sì ń gbé ibẹ̀. Lẹ́yìn náà, láti Ṣekemu ó lọ mọ odi yí ìlú Penueli ká.

26. Nígbà tí ó yá, ó rò ninu ara rẹ̀ pé, “Ìjọba yìí yóo pada di ti ilé Dafidi.”

27. Ó ní, “Bí àwọn eniyan wọnyi bá ń lọ rúbọ ní ilé OLUWA ní Jerusalẹmu, ọkàn gbogbo wọ́n lè tipa bẹ́ẹ̀ pada sẹ́yìn Rehoboamu, oluwa wọn; wọn óo sì pa mí, wọn óo sì pada tọ Rehoboamu, ọba Juda, lọ.”

28. Jeroboamu lọ gba àmọ̀ràn, ó bá fi wúrà yá ère akọ mààlúù meji, ó sì wí fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ó pẹ́ tí ẹ ti ń lọ rúbọ ní Jerusalẹmu. Ó tó gẹ́ẹ́! Ọlọrun yín, tí ó ko yín jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti nìyí.”

29. Ó gbé ọ̀kan kalẹ̀ ní ìlú Bẹtẹli ó sì gbé ekeji sí ìlú Dani.

30. Ọ̀rọ̀ yìí di ẹ̀ṣẹ̀ sí wọn lọ́rùn nítorí pé àwọn eniyan náà bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ìlú Bẹtẹli ati ìlú Dani láti jọ́sìn.

31. Jeroboamu tún kọ́ àwọn pẹpẹ ìrúbọ sí orí òkè káàkiri, ó sì yan àwọn eniyan ninu gbogbo ìdílé tí kì í ṣe ìran ẹ̀yà Lefi, láti máa ṣiṣẹ́ alufaa.

32. Jeroboamu ya ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kẹjọ sọ́tọ̀ fún àjọ̀dún, gẹ́gẹ́ bí àjọ̀dún ilẹ̀ Juda, ó sì rúbọ lórí pẹpẹ sí akọ mààlúù tí ó fi wúrà ṣe ní ìlú Bẹtẹli. Ó fi àwọn alufaa kan sibẹ, láti máa ṣe iṣẹ́ alufaa ninu àwọn ilé ìsìn tí ó kọ́ sibẹ.

33. Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kẹjọ tíí ṣe ọjọ́ tí ó yàn fún ara rẹ̀, ó lọ sí ibi pẹpẹ tí ó kọ́ sí ìlú Bẹtẹli láti rúbọ. Ó yan àjọ̀dún fún àwọn ọmọ Israẹli, ó sì lọ sun turari lórí pẹpẹ.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 12