Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 11:26-41 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Ẹnìkan tí ó tún kẹ̀yìn sí Solomoni ni ọ̀kan ninu àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ tí ń jẹ́ Jeroboamu, ọmọ Nebati, ará Sereda, ninu ẹ̀yà Efuraimu, obinrin opó kan tí ń jẹ́ Serua ni ìyá rẹ̀.

27. Ìdí tí ó fi kẹ̀yìn sí Solomoni nìyí:Nígbà tí Solomoni fi ń kún ilẹ̀ tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Jerusalẹmu, tí ó sì ń tún odi ìlú náà kọ́,

28. ó ṣe akiyesi Jeroboamu pé ó jẹ́ ọdọmọkunrin tí ó ní akitiyan. Nígbà tí Solomoni rí i bí ó ti ń ṣiṣẹ́ kára kára, ó fi ṣe olórí àwọn tí wọn ń kóni ṣiṣẹ́ tipátipá ní gbogbo agbègbè ẹ̀yà Manase ati Efuraimu.

29. Ní ọjọ́ kan, Jeroboamu ń ti Jerusalẹmu lọ sí ìrìn àjò kan, wolii Ahija, láti Ṣilo sì pàdé òun nìkan lójú ọ̀nà, ninu pápá.

30. Wolii Ahija bọ́ ẹ̀wù àwọ̀lékè tuntun tí ó wọ̀, ó ya á sí ọ̀nà mejila.

31. Ó fún Jeroboamu ni mẹ́wàá ninu rẹ̀, ó ní, “Gba mẹ́wàá yìí sọ́wọ́, nítorí OLUWA Ọlọrun Israẹli ní kí n wí fún ọ pé, òun óo gba ìjọba kúrò lọ́wọ́ Solomoni òun óo sì fi ẹ̀yà mẹ́wàá fún ọ.

32. Ṣugbọn yóo ku ẹ̀yà kan sí ọwọ́ Solomoni, nítorí ti Dafidi, iranṣẹ òun, ati nítorí Jerusalẹmu, ìlú tí òun yàn fún ara òun ninu gbogbo ilẹ̀ Israẹli.

33. Nítorí pé, Solomoni ti kọ òun sílẹ̀, ó sì ń bọ Aṣitoreti, oriṣa àwọn ará Sidoni; ati Kemoṣi, oriṣa àwọn ará Moabu; ati Milikomu oriṣa àwọn ará Amoni. Solomoni kò máa rìn ní ọ̀nà òun OLUWA, kí ó máa ṣe rere, kí ó máa pa òfin òun mọ́, kí ó sì máa tẹ̀lé ìlànà òun bí Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe.

34. Sibẹsibẹ ó ní òun kò ní gba gbogbo ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ Solomoni, òun óo fi sílẹ̀ láti máa ṣe ìjọba ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, nítorí ti Dafidi, iranṣẹ òun, ẹni tí òun yàn, tí ó pa òfin òun mọ́, tí ó sì tẹ̀lé ìlànà òun.

35. Ṣugbọn òun óo gba ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ ọmọ Solomoni, òun óo sì fún ọ ní ẹ̀yà mẹ́wàá.

36. Òun óo fi ẹ̀yà kan sílẹ̀ fún ọmọ rẹ̀, kí ọ̀kan ninu arọmọdọmọ Dafidi, iranṣẹ òun, lè máa jọba nígbà gbogbo ní Jerusalẹmu, ìlú tí òun ti yàn fún ìjọ́sìn ní orúkọ òun.

37. Ó ní ìwọ Jeroboamu ni òun óo mú, tí òun óo sì fi jọba ní Israẹli, o óo sì máa jọba lórí gbogbo agbègbè tí ó bá wù ọ́.

38. Tí o bá fetí sí gbogbo ohun tí òun pa láṣẹ fún ọ, tí o sì ń rìn ní ọ̀nà òun, tí ò ń ṣe ohun tí ó tọ́ lójú òun, tí o pa òfin òun mọ́ tí o sì ń mú àṣẹ òun ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí Dafidi, iranṣẹ òun ti ṣe, ó ní òun óo wà pẹlu rẹ, arọmọdọmọ rẹ ni yóo máa jọba lẹ́yìn rẹ, òun óo fi ìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ bí òun ti ṣe fún Dafidi; òun óo sì fi Israẹli fún ọ.

39. Ó ní òun óo jẹ arọmọdọmọ Dafidi níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Solomoni, ṣugbọn kò ní jẹ́ títí ayé.”

40. Nítorí ọ̀rọ̀ yìí, Solomoni ń wá ọ̀nà láti pa Jeroboamu, ṣugbọn Jeroboamu sá lọ sọ́dọ̀ Ṣiṣaki, ọba Ijipti, níbẹ̀ ni ó sì wà títí tí Solomoni fi kú.

41. Àwọn nǹkan yòókù tí Solomoni ṣe: gbogbo iṣẹ́ rẹ̀, ati ọgbọ́n rẹ̀, ni a kọ sinu Ìwé Ìṣe Solomoni.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 11