Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 10:3-12 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Solomoni dáhùn gbogbo àwọn ìbéèrè rẹ̀, kò sì sí ohunkohun tí ó le fún Solomoni láti ṣàlàyé.

4. Nígbà tí ọbabinrin Ṣeba rí i bí Solomoni ti gbọ́n tó, ati irú ààfin tí ó kọ́,

5. irú oúnjẹ tí ó wà lórí tabili rẹ̀, ìjókòó àwọn ìjòyè rẹ̀, ìṣesí àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati ìwọṣọ wọn, àwọn tí wọ́n ń gbé ọtí rẹ̀ ati ẹbọ sísun tí ó ń rú ninu ilé OLUWA, ẹnu yà á lọpọlọpọ.

6. Ó sọ fún Solomoni ọba pé, “Òtítọ́ ni ìròyìn tí mo gbọ́ ní ìlú mi nípa ìjọba rẹ ati ọgbọ́n rẹ.

7. Ṣugbọn n kò gbàgbọ́ títí tí mo fi wá, tí mo sì fi ojú ara mi rí i. Àwọn tí wọ́n sọ fún mi kò tilẹ̀ sọ ìdajì ohun tí mo rí. Ọgbọ́n, ati ọrọ̀ rẹ pọ̀ rékọjá ohun tí mo gbọ́ lọ.

8. Àwọn iyawo rẹ ṣe oríire; bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn iranṣẹ rẹ wọnyi tí wọn ń wà lọ́dọ̀ rẹ nígbà gbogbo, tí wọn ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n rẹ!

9. Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun rẹ, ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí ọ, tí ó sì fi ọ́ jọba Israẹli. Nítorí ìfẹ́ ayérayé tí ó ní sí Israẹli ni ó ṣe fi ọ́ jọba lórí wọn, kí o lè máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ati ti òdodo.”

10. Lẹ́yìn náà, ọbabinrin Ṣeba fún Solomoni ọba ní ọgọfa (120) ìwọ̀n talẹnti wúrà, ati ọpọlọpọ turari olóòórùn dídùn, ati àwọn òkúta olówó iyebíye. Turari tí ọbabinrin Ṣeba fún Solomoni pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé Solomoni kò rí irú rẹ̀ gbà ní ẹ̀bùn mọ́.

11. Àwọn ọkọ̀ ojú omi Hiramu ọba, tí ó kó wúrà wá láti Ofiri kó ọpọlọpọ igi alimugi ati òkúta olówó iyebíye bọ̀ pẹlu.

12. Solomoni ọba fi igi alimugi náà ṣe òpó ilé OLUWA ati ti ààfin rẹ̀. Ó tún lò ninu wọn, ó fi ṣe ohun èlò orin tí wọ́n ń pè ní hapu ati gòjé fún àwọn akọrin rẹ̀. Ẹnikẹ́ni kò rí irú igi alimugi bẹ́ẹ̀ mọ́ ní ilẹ̀ Israẹli títí di òní olónìí.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 10