Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 10:22-29 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Ó ní ọpọlọpọ ọkọ̀ ojú omi Taṣiṣi tí wọ́n máa ń bá àwọn ọkọ̀ ojú omi Hiramu lọ sí òkè òkun. Ọdún kẹta kẹta ni wọ́n máa ń pada dé, wọn á sì máa kó ọpọlọpọ wúrà, ati fadaka, eyín erin, ìnàkí, ati ẹyẹ ọ̀kín bọ̀.

23. Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ọba ṣe lọ́rọ̀, tí ó sì gbọ́n ju gbogbo ọba yòókù lọ.

24. Gbogbo aráyé a sì máa fẹ́ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, láti tẹ́tí sí ọgbọ́n tí Ọlọrun fún un.

25. Ní ọdọọdún ni ọpọlọpọ eniyan máa ń mú ọpọlọpọ ẹ̀bùn àwọn nǹkan tí wọ́n fi fadaka ati wúrà ṣe wá sọ́dọ̀ rẹ̀, pẹlu ẹ̀wù, ati turari olóòórùn dídùn, ẹṣin, ati ìbaaka.

26. Ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹlẹ́ṣin ni Solomoni ọba kó jọ, kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ jẹ́ egbeje (1,400), àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbaafa (1,200). Ó fi apá kan ninu wọn sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ ní Jerusalẹmu, ó sì kó àwọn yòókù sí ìlú ńláńlá tí ó ń kó àwọn kẹ̀kẹ́ ogun sí káàkiri.

27. Solomoni ọba mú kí fadaka pọ̀ ní Jerusalẹmu bí òkúta, igi Kedari sì pọ̀ bí igi Sikamore tí ó wà káàkiri ní Ṣefela ní ẹsẹ̀ òkè Juda.

28. Láti Ijipti ati Kue ni àwọn oníṣòwò Solomoni tií máa bá a ra àwọn ẹṣin wá.

29. Ẹgbẹta (600) ìwọ̀n ṣekeli fadaka ni wọ́n máa ń ra kẹ̀kẹ́ ogun kan láti Ijipti, wọn a sì máa ra ẹṣin kan ní aadọjọ (150) ìwọ̀n ṣekeli fadaka. Àwọn oníṣòwò Solomoni níí máa ń tà wọ́n fún àwọn ọba ilẹ̀ Hiti ati àwọn ọba ilẹ̀ Siria.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 10