Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 10:15-25 BIBELI MIMỌ (BM)

15. láìka èyí tí àwọn oníṣòwò ń san fún un, èyí tí ń wá láti ibi òwò rẹ̀, ati èyí tí àwọn ọba Arabia ati àwọn gomina ilẹ̀ Israẹli ń san.

16. Solomoni ṣe igba (200) apata wúrà ńláńlá, wúrà tí ó lò fún ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbẹta (600) ìwọ̀n ṣekeli.

17. Ó sì tún ṣe ọọdunrun (300) apata wúrà kéékèèké, wúrà tí ó lò fún ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìwọ̀n mina mẹta mẹta. Solomoni ọba kó gbogbo apata wọnyi sinu Ilé Igbó Lẹbanoni.

18. Ó fi eyín erin ṣe ìtẹ́ ńlá kan, ó sì yọ́ wúrà dáradára bò ó.

19. Ìtẹ́ náà ní àtẹ̀gùn mẹfa, ère orí ọmọ mààlúù sì wà lẹ́yìn ìtẹ́ náà. Ère kinniun wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji ibi tí wọn ń gbé apá lé lára ìtẹ́ náà.

20. Ère kinniun mejila wà lórí àwọn àtẹ̀gùn mẹfẹẹfa, meji meji lórí àtẹ̀gùn kọ̀ọ̀kan, ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji àtẹ̀gùn náà; kò sí ìjọba orílẹ̀-èdè kankan tí ó tún ní irú ìtẹ́ náà.

21. Wúrà ni wọ́n fi ṣe gbogbo ife ìmumi Solomoni, ati gbogbo àwọn ohun èlò tí ó wà ninu Ilé Igbó Lẹbanoni. Kò sí ẹyọ kan ninu wọn tí wọ́n fi fadaka ṣe, nítorí pé fadaka kò já mọ́ nǹkankan ní àkókò Solomoni.

22. Ó ní ọpọlọpọ ọkọ̀ ojú omi Taṣiṣi tí wọ́n máa ń bá àwọn ọkọ̀ ojú omi Hiramu lọ sí òkè òkun. Ọdún kẹta kẹta ni wọ́n máa ń pada dé, wọn á sì máa kó ọpọlọpọ wúrà, ati fadaka, eyín erin, ìnàkí, ati ẹyẹ ọ̀kín bọ̀.

23. Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ọba ṣe lọ́rọ̀, tí ó sì gbọ́n ju gbogbo ọba yòókù lọ.

24. Gbogbo aráyé a sì máa fẹ́ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, láti tẹ́tí sí ọgbọ́n tí Ọlọrun fún un.

25. Ní ọdọọdún ni ọpọlọpọ eniyan máa ń mú ọpọlọpọ ẹ̀bùn àwọn nǹkan tí wọ́n fi fadaka ati wúrà ṣe wá sọ́dọ̀ rẹ̀, pẹlu ẹ̀wù, ati turari olóòórùn dídùn, ẹṣin, ati ìbaaka.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 10