Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 1:12-25 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Wá, jẹ́ kí n gbà ọ́ nímọ̀ràn kan, bí o bá fẹ́ràn ẹ̀mí rẹ, ati ẹ̀mí Solomoni, ọmọ rẹ.

13. Tọ Dafidi ọba lọ lẹsẹkẹsẹ, kí o sì bi í pé, ṣebí òun ni ó fi ìbúra ṣe ìlérí fún ọ pé Solomoni ọmọ rẹ ni yóo jọba lẹ́yìn rẹ̀? Kí ló dé tí Adonija fi di ọba?

14. Bí o bá ti ń bá ọba sọ̀rọ̀ ni n óo wọlé, n óo sì sọ pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.”

15. Batiṣeba bá wọlé tọ ọba lọ ninu yàrá rẹ̀. (Ọba ti di arúgbó ní àkókò yìí, Abiṣagi ará Ṣunemu ni ó ń tọ́jú rẹ̀.)

16. Batiṣeba wólẹ̀ níwájú ọba, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Ọba bá bi í pé, “Kí ni o fẹ́ gbà?”

17. Ó dá ọba lóhùn, ó ní, “Kabiyesi, ìwọ ni o ṣe ìlérí fún èmi iranṣẹbinrin rẹ, tí o sì fi orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ búra pé, Solomoni ọmọ mi ni yóo jọba lẹ́yìn rẹ.

18. Ṣugbọn Adonija ti fi ara rẹ̀ jọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kabiyesi kò mọ nǹkankan nípa rẹ̀.

19. Ó ti fi ọpọlọpọ akọ mààlúù, ati aguntan, ati àbọ́pa mààlúù rúbọ. Ó pe gbogbo àwọn ọmọ ọba lọkunrin, ati Abiatari alufaa, ati Joabu balogun rẹ síbi àsè rẹ̀, ṣugbọn kò pe Solomoni, iranṣẹ rẹ.

20. Ojú rẹ ni gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ń wò báyìí, pé kí o fa ẹni tí o bá fẹ́ kí ó jọba lẹ́yìn rẹ kalẹ̀ fún wọn.

21. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbàrà tí kabiyesi bá ti kú tán, bí wọ́n ti ń ṣe àwọn arúfin ni wọn yóo ṣe èmi ati Solomoni ọmọ rẹ.”

22. Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni Natani wolii wọlé.

23. Wọ́n bá sọ fún ọba pé Natani wolii ti dé. Nígbà tí Natani wọlé, ó wólẹ̀ níwájú ọba, ó sì dojúbolẹ̀.

24. Ó wí pé, “Kabiyesi, ṣé o ti kéde pé Adonija ni yóo jọba lẹ́yìn rẹ ni?

25. Ní òní olónìí yìí, ó ti fi ọpọlọpọ akọ mààlúù, ati aguntan, ati àbọ́pa mààlúù rúbọ. Ó pe gbogbo àwọn ọmọ ọba lọkunrin, ati Joabu balogun, ati Abiatari, alufaa. Bí mo ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí, gbogbo wọn wà níbi tí wọ́n ti ń jẹ, tí wọn ń mu, tí wọn ń pariwo pé, ‘Kí Adonija ọba kí ó pẹ́.’

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 1