Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 8:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Eliṣa sọ fún obinrin ará Ṣunemu, ẹni tí Eliṣa jí ọmọ rẹ̀ tí ó kú pé, “OLUWA yóo rán ìyàn sí ilẹ̀ yìí fún ọdún meje, nítorí náà, kí ìwọ ati ẹbí rẹ lọ máa gbé ní ilẹ̀ mìíràn.”

2. Obinrin náà gbọ́ ọ̀rọ̀ Eliṣa, òun ati ẹbí rẹ̀ sì lọ ń gbé ilẹ̀ àwọn ará Filistia fún ọdún meje.

3. Lẹ́yìn ọdún keje, obinrin náà pada sí Israẹli, ó sì lọ sọ́dọ̀ ọba láti bẹ̀ ẹ́ pé kí ó dá ilé ati ilẹ̀ òun pada.

4. Ó bá ọba tí ó ń bá Gehasi iranṣẹ Eliṣa sọ̀rọ̀; ọba fẹ́ mọ̀ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu Eliṣa.

5. Bí Gehasi ti ń sọ fún ọba bí Eliṣa ṣe jí òkú dìde, ni obinrin tí Eliṣa jí òkú ọmọ rẹ̀ dìde wá sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún ọba. Gehasi sọ fún ọba pé, “Olúwa mi, obinrin náà nìyí, ọmọkunrin rẹ̀ tí Eliṣa jí dìde náà sì nìyí.”

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 8