Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 4:42-44 BIBELI MIMỌ (BM)

42. Ọkunrin kan wá láti Baaliṣaliṣa, ó mú burẹdi àkọ́so èso wá fún eniyan Ọlọrun, ati ogún burẹdi tí a fi ọkà-baali ṣe ati ṣiiri ọkà tuntun ninu àpò rẹ̀. Eliṣa bá wí pé, “Ẹ kó wọn fún àwọn ọmọkunrin, kí wọ́n jẹ ẹ́.”

43. Ṣugbọn iranṣẹ rẹ̀ wí pé, “Báwo ni n óo ṣe wá gbé èyí kalẹ̀ níwájú ọgọrun-un eniyan láti jẹ?”Eliṣa tún ní, “Kó wọn fún àwọn ọmọkunrin kí wọ́n jẹ ẹ́, nítorí pé OLUWA ní, ‘Wọn yóo jẹ, yóo sì ṣẹ́kù.’ ”

44. Iranṣẹ náà bá gbé oúnjẹ náà kalẹ̀ níwájú àwọn ọmọkunrin náà, wọ́n jẹ, ó sì ṣẹ́kù gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 4