Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 4:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Iyawo ọ̀kan ninu àwọn ọmọ àwọn wolii tọ Eliṣa lọ, ó sì sọ fún un pé, “Olúwa mi, iranṣẹ rẹ, ọkọ mi, ti kú, gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀, ó jẹ́ ẹni tí ó bẹ̀rù OLUWA nígbà ayé rẹ̀. Ẹnìkan tí ó jẹ lówó kí ó tó kú fẹ́ kó àwọn ọmọkunrin mi mejeeji lẹ́rú, nítorí gbèsè baba wọn.”

2. Eliṣa bèèrè pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ? Sọ ohun tí o ní nílé fún mi.”Obinrin náà dáhùn pé, “N kò ní ohunkohun, àfi ìkòkò òróró kan.”

3. Eliṣa sọ fún un pé, “Lọ yá ọpọlọpọ ìkòkò lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò rẹ.

4. Lẹ́yìn náà, kí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ wọlé, nígbà tí ẹ bá sì ti ti ìlẹ̀kùn yín tán, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí da òróró náà sinu àwọn ìkòkò náà, kí ẹ sì máa gbé wọn sí ẹ̀gbẹ́ kan bí wọ́n bá ti ń kún.”

5. Obinrin náà lọ sinu ilé rẹ̀ pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n sì ti ìlẹ̀kùn wọn; ó bá bẹ̀rẹ̀ sí da òróró náà sinu àwọn ìkòkò náà bí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe ń gbé wọn wá.

6. Nígbà tí gbogbo àwọn ìkòkò náà kún, obinrin náà bèèrè bóyá ìkòkò kù, àwọn ọmọ rẹ̀ sì dáhùn pé ó ti tán, òróró náà sì dá.

7. Ó bá pada lọ sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún wolii Eliṣa. Eliṣa wí fún un pé, “Lọ ta àwọn òróró náà kí o sì san gbèsè rẹ ninu rẹ̀, kí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ máa ná ìyókù.”

8. Ní ọjọ́ kan Eliṣa lọ sí Ṣunemu, níbi tí obinrin ọlọ́rọ̀ kan ń gbé; obinrin náà sì pe Eliṣa wọlé kí ó wá jẹun. Láti ìgbà náà, ilé obinrin yìí ni Eliṣa ti máa ń jẹun ní Ṣunemu.

9. Obinrin náà sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, “Mo wòye pé ọkunrin tí ó ń wá síbí yìí jẹ́ ẹni mímọ́ Ọlọ́run.

10. Jẹ́ kí á ṣe yàrá kékeré kan sí òkè ilé wa, kí á gbé ibùsùn, tabili, àga ati fìtílà sibẹ, kí ó lè máa dé sibẹ nígbàkúùgbà tí ó bá wá síbí.”

11. Ní ọjọ́ kan tí Eliṣa pada lọ sí Ṣunemu, ó wọ inú yàrá náà lọ láti sinmi.

12. Ó bá rán Gehasi iranṣẹ rẹ̀ kí ó pe obinrin náà wá. Nígbà tí ó wọlé ó dúró níwájú Eliṣa.

13. Eliṣa sọ fún Gehasi kí ó bèèrè lọ́wọ́ obinrin náà ohun tí ó fẹ́ kí òun ṣe fún un, fún gbogbo nǹkan tí ó ti ṣe fún àwọn. Ó ní, bóyá ó fẹ́ kí òun sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún ọba ni tabi fún balogun? Obinrin náà dáhùn pé ààrin àwọn eniyan òun ni òun ń gbé.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 4