Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 3:25-27 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Wọ́n pa àwọn ìlú wọn run, gbogbo ilẹ̀ oko tí ó dára ni wọ́n da òkúta sí títí tí gbogbo wọn fi kún. Wọ́n dí gbogbo orísun omi, wọ́n sì gé gbogbo àwọn igi dáradára. Kiri Heresi tíí ṣe olú-ìlú wọn nìkan ni wọn kò pa run, ṣugbọn àwọn tí wọn ń ta kànnàkànnà yí i ká, wọ́n sì ṣẹgun rẹ̀.

26. Nígbà tí ọba Moabu rí i pé ogun náà le pupọ, ó mú ẹẹdẹgbẹrin (700) ọkunrin tí wọ́n ń lo idà, ó gbìyànjú láti la ààrin ogun kọjá níwájú ọba Edomu, ṣugbọn kò ṣeéṣe.

27. Nítorí náà, ó fi àkọ́bí rẹ̀ ọkunrin, tí ó yẹ kí ó jọba lẹ́yìn rẹ̀ rú ẹbọ sísun sí oriṣa Moabu, ní orí odi ìlú náà. Ibinu ńlá dé bá àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì fi í sílẹ̀, wọ́n pada lọ sí ilẹ̀ wọn.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 3