Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 25:16-30 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Bàbà tí Solomoni fi ṣe àwọn òpó mejeeji, agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ kọjá wíwọ̀n.

17. Gíga ọ̀kan ninu àwọn òpó náà jẹ́ igbọnwọ mejidinlogun, ọpọ́n idẹ tí ó wà lórí rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mẹta, wọ́n fi bàbà ṣe ẹ̀wọ̀n bí ẹ̀gbà ọrùn ati pomegiranate yí ọpọ́n náà ká, òpó keji sì dàbí ti àkọ́kọ́ pẹlu ẹ̀wọ̀n bàbà náà.

18. Olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni mú Seraya olórí alufaa, ati Sefanaya igbákejì alufaa, ati àwọn aṣọ́nà mẹta.

19. Ó sì mú ọ̀gágun tí ń ṣe àkóso àwọn ọmọ ogun ní ìlú ati àwọn aṣojú ọba marun-un tí ó rí ninu ìlú ati akọ̀wé olórí ogun, tí ń kọ orúkọ àwọn eniyan ilẹ̀ náà sílẹ̀ fún ogun jíjà, ati ọgọta ọkunrin tí ó rí ninu ìlú náà.

20. Nebusaradani kó gbogbo wọn lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila.

21. Ọba Babiloni lù wọ́n, ó sì pa wọ́n sórí ilẹ̀ Hamati.Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe kó Juda ní ìgbèkùn kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀.

22. Nebukadinesari ọba Babiloni yan Gedalaya ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani ní gomina lórí àwọn tí wọ́n kù ní ilẹ̀ Juda.

23. Nígbà tí àwọn olórí ogun tí wọ́n wà ní ìgbèríko pẹlu àwọn ọmọ ogun wọn gbọ́ pé ọba Babiloni ti fi Gedalaya ọmọ Ahikamu ṣe Gomina ní ilẹ̀ Juda, àwọn pẹlu àwọn eniyan wọn wá sí ọ̀dọ̀ Gedalaya ní Misipa. Àwọn tí wọ́n wá ni Iṣimaeli, ọmọ Netanaya, Johanani, ọmọ Karea, Seraya, ọmọ Tanhumeti, ará Netofa, ati Jaasanaya, ọmọ ará Maakati.

24. Gedalaya bá búra fún wọn, ó ní: “Ẹ má ṣe bẹ̀rù nítorí àwọn olórí Kalidea, ẹ máa gbé ilẹ̀ náà kí ẹ sì máa sin ọba Babiloni, yóo sì dára fun yín.”

25. Ṣugbọn ní oṣù keje Iṣimaeli, ọmọ Netanaya, ọmọ Eliṣama, láti ìdílé ọba, pẹlu àwọn ọkunrin mẹ́wàá dojú kọ Gedalaya, wọ́n sì pa òun, ati àwọn Juu ati àwọn ará Kalidea tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ní Misipa.

26. Ni gbogbo wọn, àtọmọdé, àtàgbà, ati àwọn olórí ogun bá gbéra, wọ́n kó lọ sí Ijipti, nítorí ẹ̀rù àwọn ará Kalidea bà wọ́n.

27. Ní ọdún kẹtadinlogoji lẹ́yìn tí wọ́n ti mú Jehoiakini ọba Juda lọ sí ìgbèkùn, ní ọjọ́ kẹtadinlọgbọn oṣù kejila ọdún náà, Efilimerodaki, ọba Babiloni, gbé ọ̀rọ̀ Jehoiakini yẹ̀wò, ní ọdún tí ó gorí oyè, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n tú u sílẹ̀ kúrò ní ẹ̀wọ̀n.

28. Ó bá a sọ̀rọ̀ rere, ó sì fi sí ipò tí ó ga ju ti gbogbo àwọn ọba tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ní Babiloni lọ.

29. Jehoiakini bọ́ aṣọ ẹ̀wọ̀n kúrò lọ́rùn, ó sì ń bá ọba jẹun lórí tabili ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

30. Ọba Babiloni rí i pé òun ń pèsè ohun tí ó nílò ní ojoojumọ fún un, títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 25