Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 25:13-23 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Àwọn ọmọ ogun Kalidea fọ́ àwọn òpó bàbà tí ó wà ninu ilé OLUWA ati agbada bàbà ńlá tí ó wà ninu ilé OLUWA pẹlu ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀, wọ́n fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́, wọ́n sì kó gbogbo bàbà wọn lọ sí Babiloni.

14. Wọ́n kó àwọn ìkòkò, àwọn ọ̀kọ̀, àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi ń pa iná lẹ́nu àtùpà, àwọn àwo turari ati àwọn ohun èlò bàbà tí wọ́n máa ń lò fún ìsìn ninu ilé OLUWA.

15. Bákan náà, wọ́n kó àwọn àwo ìfọnná, ati àwọn àwo kòtò, gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti wúrà ati fadaka, ni olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni kó lọ.

16. Bàbà tí Solomoni fi ṣe àwọn òpó mejeeji, agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ kọjá wíwọ̀n.

17. Gíga ọ̀kan ninu àwọn òpó náà jẹ́ igbọnwọ mejidinlogun, ọpọ́n idẹ tí ó wà lórí rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ mẹta, wọ́n fi bàbà ṣe ẹ̀wọ̀n bí ẹ̀gbà ọrùn ati pomegiranate yí ọpọ́n náà ká, òpó keji sì dàbí ti àkọ́kọ́ pẹlu ẹ̀wọ̀n bàbà náà.

18. Olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni mú Seraya olórí alufaa, ati Sefanaya igbákejì alufaa, ati àwọn aṣọ́nà mẹta.

19. Ó sì mú ọ̀gágun tí ń ṣe àkóso àwọn ọmọ ogun ní ìlú ati àwọn aṣojú ọba marun-un tí ó rí ninu ìlú ati akọ̀wé olórí ogun, tí ń kọ orúkọ àwọn eniyan ilẹ̀ náà sílẹ̀ fún ogun jíjà, ati ọgọta ọkunrin tí ó rí ninu ìlú náà.

20. Nebusaradani kó gbogbo wọn lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila.

21. Ọba Babiloni lù wọ́n, ó sì pa wọ́n sórí ilẹ̀ Hamati.Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe kó Juda ní ìgbèkùn kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀.

22. Nebukadinesari ọba Babiloni yan Gedalaya ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani ní gomina lórí àwọn tí wọ́n kù ní ilẹ̀ Juda.

23. Nígbà tí àwọn olórí ogun tí wọ́n wà ní ìgbèríko pẹlu àwọn ọmọ ogun wọn gbọ́ pé ọba Babiloni ti fi Gedalaya ọmọ Ahikamu ṣe Gomina ní ilẹ̀ Juda, àwọn pẹlu àwọn eniyan wọn wá sí ọ̀dọ̀ Gedalaya ní Misipa. Àwọn tí wọ́n wá ni Iṣimaeli, ọmọ Netanaya, Johanani, ọmọ Karea, Seraya, ọmọ Tanhumeti, ará Netofa, ati Jaasanaya, ọmọ ará Maakati.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 25