Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 23:25-37 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Ṣáájú Josaya ati lẹ́yìn rẹ̀, kò sí ọba kankan tí ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀, gbogbo ẹ̀mí rẹ̀ ati gbogbo agbára rẹ̀ sin Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu gbogbo òfin Mose.

26. Ṣugbọn sibẹsibẹ ibinu gbígbóná OLUWA tí ó ti ru sókè sí Juda nítorí ìwà burúkú Manase kò rọlẹ̀.

27. OLUWA sọ pé, “N óo ṣe ohun tí mo ṣe sí Israẹli sí Juda, n óo pa àwọn eniyan Juda run, n óo sì kọ Jerusalẹmu, ìlú tí mo yàn sílẹ̀, ati ilé OLUWA tí mo yàn fún ìsìn mi.”

28. Gbogbo nǹkan yòókù tí Josaya ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

29. Ní àkókò tí Josaya jọba ni Neko, ọba Ijipti kó ogun rẹ̀ wá sí etí odò Yufurate láti ran ọba Asiria lọ́wọ́. Josaya pinnu láti dá ogun Ijipti pada ní Megido, ṣugbọn ó kú lójú ogun náà.

30. Àwọn olórí ogun rẹ̀ gbé òkú rẹ̀ sinu kẹ̀kẹ́ ogun kan láti Megido wọn gbé e wá sí Jerusalẹmu, wọ́n sì sin ín sinu ibojì rẹ̀.Àwọn eniyan Juda sì fi òróró yan Jehoahasi ọmọ rẹ̀ ní ọba.

31. Ẹni ọdún mẹtalelogun ni Jehoahasi nígbà tí ó jọba ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹta. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hamutali, ọmọ Jeremaya, ará Libina.

32. Òun náà ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá rẹ̀.

33. Neko ọba Ijipti mú Jehoahasi ní ìgbèkùn ní Ribila ní ilẹ̀ Hamati, kí ó má baà jọba lórí Jerusalẹmu mọ́. Ó sì mú kí Juda san ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka ati ìwọ̀n talẹnti wúrà kan bí ìṣákọ́lẹ̀.

34. Neko sì fi Eliakimu, ọmọ Josaya, jọba dípò rẹ̀, ṣugbọn ó yí orúkọ rẹ̀ pada sí Jehoiakimu. Neko mú Jehoahasi lọ sí Ijipti, ibẹ̀ ni ó sì kú sí.

35. Jehoiakimu ọba gba owó orí lọ́wọ́ àwọn eniyan gẹ́gẹ́ bí ọrọ̀ wọn ti pọ̀ tó, láti rí owó san ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba Ijipti gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún un.

36. Jehoiakimu jẹ́ ẹni ọdún mẹẹdọgbọn nígbà tí ó jọba, ó sì jọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanla. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Sebida, ọmọ Pedaaya, láti ìlú Ruma.

37. Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá rẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 23