Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 21:17-26 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Gbogbo nǹkan yòókù tí Manase ṣe ati àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

18. Manase kú, wọ́n sì sin ín sinu ọgba Usa tí ó wà ní ààfin. Amoni ọmọ rẹ̀, sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

19. Ẹni ọdún mejilelogun ni Amoni nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún meji. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Meṣulemeti ọmọ Harusi ará Jotiba.

20. Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA bí Manase, baba rẹ̀ ti ṣe.

21. Ó tẹ̀ sí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀, ó sì bọ àwọn ère tí baba rẹ̀ bọ.

22. Ó kọ OLUWA Ọlọrun àwọn baba ńlá rẹ̀ sílẹ̀, kò sì júbà àṣẹ rẹ̀.

23. Àwọn iranṣẹ rẹ̀ dìtẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì pa á ní ààfin rẹ̀.

24. Àwọn eniyan Juda pa àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ mọ́ Amoni ọba, wọ́n sì fi Josaya ọmọ rẹ̀ jọba lẹ́yìn rẹ̀.

25. Gbogbo nǹkan yòókù tí Amoni ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

26. Wọ́n sin òkú rẹ̀ sinu ibojì tí ó wà ninu ọgbà Usa ní ààfin. Josaya, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 21