Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 20:14-21 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Nígbà náà ni wolii Aisaya lọ sí ọ̀dọ̀ Hesekaya, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni àwọn ọkunrin wọnyi ti wá, kí ni wọ́n sì sọ fún ọ?”Hesekaya dáhùn pé, “Ọ̀nà jíjìn ni wọ́n ti wá, láti Babiloni.”

15. Aisaya bá tún bèèrè pé, “Kí ni wọ́n rí ninu ààfin rẹ?”Ọba dáhùn, ó ní, “Kò sí ohun kan ninu ilé ìṣúra tí n kò fi hàn wọ́n.”

16. Nígbà náà ni Aisaya sọ fún ọba pé, “OLUWA ní,

17. ‘Àkókò kan ń bọ̀ tí wọn yóo kó gbogbo ohun tí ó wà ninu ààfin rẹ lọ sí Babiloni, gbogbo ohun tí àwọn baba ńlá rẹ ti kó jọ látẹ̀yìnwá títí di òní ni wọn óo kó lọ, wọn kò ní fi nǹkankan sílẹ̀.

18. Wọn yóo kó ninu àwọn ọmọ rẹ lọ fi ṣe ìwẹ̀fà ní ààfin ọba Babiloni.’ ”

19. Hesekaya sọ fún Aisaya pé, “Ọ̀rọ̀ OLUWA tí o sọ dára.” Nítorí ó wí ninu ara rẹ̀ pé, alaafia ati ìfọ̀kànbalẹ̀ yóo sá wà ní àkókò tòun.

20. Gbogbo nǹkan yòókù tí Hesekaya ṣe, ìwà akọni rẹ̀ ati bí ó ti ṣe adágún omi ati ọ̀nà omi wọ inú ìlú ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

21. Hesekaya kú, wọ́n sì sin ín sinu ibojì àwọn baba rẹ̀; Manase ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 20