Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 20:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní àkókò kan Hesekaya ṣàìsàn tóbẹ́ẹ̀ tí ó fẹ́rẹ̀ kú. Wolii Aisaya ọmọ Amosi, wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sọ fún un pé, “OLUWA ní kí o palẹ̀ ilé rẹ mọ́ nítorí pé kíkú ni o óo kú, o kò ní yè.”

2. Hesekaya bá kọjú sí ògiri, ó sì gbadura sí OLUWA, ó ní,

3. “Mo bẹ̀ ọ́ OLUWA, ranti bí mo ti sìn ọ́ pẹlu òtítọ́ ati ọkàn pípé, ati bí mo ti ń ṣe ohun tí o fẹ́.” Ó sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.

4. Aisaya jáde kúrò lọ́dọ̀ ọba, ṣugbọn kí ó tó jáde kúrò ní àgbàlá ààfin, OLUWA sọ fún un pé,

5. “Pada lọ sọ́dọ̀ Hesekaya, olórí àwọn eniyan mi, kí o sì sọ fún un pé, ‘Èmi OLUWA Ọlọrun Dafidi baba ńlá rẹ̀ ti gbọ́ adura rẹ̀, mo sì ti rí omijé rẹ̀. N óo wò ó sàn, ní ọjọ́ kẹta, yóo lọ sí ilé OLUWA,

6. n óo sì jẹ́ kí ó gbé ọdún mẹẹdogun sí i. N óo gba òun ati Jerusalẹmu lọ́wọ́ ọba Asiria. N óo sì dáàbò bo ìlú yìí nítorí tèmi fúnra mi ati nítorí ìlérí tí mo ṣe fún Dafidi, iranṣẹ mi.’ ”

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 20