Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 15:33-38 BIBELI MIMỌ (BM)

33. Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni nígbà tí ó jọba, ó sì jọba fún ọdún mẹrindinlogun ní Jerusalẹmu. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jeruṣa, ọmọ Sadoku.

34. Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA nítorí pé ó tẹ̀ sí ọ̀nà Usaya, baba rẹ̀.

35. Ṣugbọn kò pa àwọn pẹpẹ ìrúbọ run, àwọn eniyan ṣì ń rú ẹbọ, wọ́n sì ń sun turari níbẹ̀. Òun ni ó kọ́ ẹnu ọ̀nà apá ìhà àríwá ilé OLUWA.

36. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jotamu ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

37. Ní àkókò tí ó jọba ni OLUWA bẹ̀rẹ̀ sí rán Resini, ọba Siria, ati Peka, ọmọ Remalaya, tí í ṣe ọba Israẹli, láti gbógun ti Juda.

38. Jotamu kú, wọ́n sin ín sinu ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi; Ahasi ọmọ rẹ̀, sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 15