Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 14:11-26 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ṣugbọn Amasaya kọ̀ kò gbọ́, nítorí náà, Jehoaṣi ọba Israẹli kó ogun lọ pàdé Amasaya ọba Juda ní Beti Ṣemeṣi tí ó wà ní Juda.

12. Israẹli ṣẹgun Juda, gbogbo àwọn ọmọ ogun Juda sì pada sí ilé wọn.

13. Ọwọ́ Jehoaṣi tẹ Amasaya, lẹ́yìn náà, ó lọ sí Jerusalẹmu, ó wó odi Jerusalẹmu lulẹ̀ láti Ẹnubodè Efuraimu títí dé Ẹnubodè Igun, gbogbo rẹ̀ jẹ́ irinwo igbọnwọ (400 mita).

14. Ó kó gbogbo fadaka ati wúrà tí ó rí ati gbogbo àwọn ohun èlò ilé OLUWA ati gbogbo ohun tí ó níye lórí ní ààfin, ó sì pada sí Samaria.

15. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoaṣi ṣe, ati ìwà akọni rẹ̀ ninu ogun tí ó bá Amasaya jà, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

16. Jehoaṣi kú, wọ́n sin òkú rẹ̀ sinu ibojì àwọn ọba ní Samaria. Jeroboamu ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

17. Amasaya ọba, ọmọ Joaṣi gbé ọdún mẹẹdogun lẹ́yìn ikú Jehoaṣi ọba Israẹli.

18. Gbogbo nǹkan yòókù tí Amasaya ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

19. Wọ́n dìtẹ̀ mọ́ Amasaya Ọba ní Jerusalẹmu, ó sì sá lọ sí Lakiṣi. Ṣugbọn wọ́n rán eniyan lọ bá a níbẹ̀, wọ́n sì pa á.

20. Wọ́n gbé òkú rẹ̀ sórí ẹṣin wá sí Jerusalẹmu, wọ́n sì sin ín sinu ibojì àwọn ọba, ní ìlú Dafidi.

21. Àwọn eniyan Juda sì fi Asaraya, ọmọ rẹ̀, jọba. Ẹni ọdún mẹrindinlogun ni, nígbà tí ó jọba.

22. Asaraya tún ìlú Elati kọ́, ó sì dá a pada fún Juda lẹ́yìn ikú baba rẹ̀.

23. Ní ọdún kẹẹdogun tí Amasaya ọmọ Joaṣi jọba ní Juda ni Jeroboamu, ọmọ Jehoaṣi, ọba Israẹli jọba ní Samaria, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mọkanlelogoji.

24. Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA; ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli dẹ́ṣẹ̀.

25. Ó gba gbogbo ilẹ̀ Israẹli pada láti ẹnubodè Hamati títí dé Òkun Araba, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ láti ẹnu wolii rẹ̀, Jona, ọmọ Amitai, ará Gati Heferi.

26. OLUWA rí i pé ìpọ́njú àwọn ọmọ Israẹli pọ̀, kò sì sí ẹni tí ìpọ́njú náà kò kàn, ati ẹrú ati ọmọ, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó lè ràn wọ́n lọ́wọ́.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 14