Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 13:13-25 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Jehoaṣi kú, wọ́n sì sin ín sinu ibojì àwọn ọba Israẹli ní Samaria. Jeroboamu ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

14. Nígbà tí wolii Eliṣa wà ninu àìsàn tí ó le, tí ó sì ń kú lọ, Jehoaṣi, ọba Israẹli lọ bẹ̀ ẹ́ wò, nígbà tí ó rí Eliṣa, ó sọkún, ó sì ń kígbe pé, “Baba mi, baba mi! Ìwọ tí o jẹ́ alátìlẹyìn pataki fún Israẹli!”

15. Eliṣa bá sọ fún un pé kí ó mú ọrun ati ọfà, ó sì mú wọn.

16. Eliṣa sọ fún un pé kí ó múra láti ta ọfà náà, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Eliṣa gbé ọwọ́ lé ọwọ́ ọba,

17. ó ní kí ọba ṣí fèrèsé, kí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn, ọba sì ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, Eliṣa pàṣẹ fún un pé kí ó ta ọfà náà. Bí ọba ti ta ọfà ni Eliṣa ń wí pé, “Ọfà ìṣẹ́gun OLUWA, ọfà ìṣẹ́gun lórí Siria! Nítorí pé o óo bá àwọn Siria jagun ní Afeki títí tí o óo fi ṣẹgun wọn.”

18. Eliṣa tún ní kí ọba máa ta àwọn ọfà yòókù sílẹ̀. Nígbà tí ó ta á lẹẹmẹta, ó dáwọ́ dúró.

19. Èyí bí Eliṣa ninu, ó sì sọ fún ọba pé, “Bí ó bá jẹ́ pé o ta ọfà náà nígbà marun-un tabi mẹfa ni, ò bá ṣẹgun Siria patapata, ṣugbọn báyìí, ìgbà mẹta ni o óo ṣẹgun wọn.”

20. Eliṣa kú, wọ́n sì sin òkú rẹ̀.Ní ọdọọdún ni àwọn ọmọ ogun Moabu máa ń gbógun ti ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli.

21. Ní ìgbà kan, bí wọ́n ti fẹ́ máa sìnkú ọkunrin kan, wọ́n rí i tí àwọn ọmọ ogun Moabu ń bọ̀, wọ́n bá ju òkú náà sinu ibojì Eliṣa. Bí ọkunrin náà ti fi ara kan egungun Eliṣa, ó sọjí, ó sì dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀.

22. Hasaeli ọba Siria kò fi àwọn ọmọ Israẹli lọ́kàn balẹ̀ ní gbogbo àkókò ìjọba Jehoahasi.

23. Ṣugbọn OLUWA ṣàánú fún wọn, ó sì yipada sí wọn nítorí majẹmu rẹ̀ pẹlu Abrahamu, ati Isaaki ati Jakọbu; kò sì gbàgbé àwọn eniyan rẹ̀.

24. Nígbà tí Hasaeli Ọba kú, Benhadadi ọmọ rẹ̀ jọba lẹ́yìn rẹ̀.

25. Jehoaṣi ọba, ọmọ Jehoahasi, ṣẹgun Benhadadi ní ìgbà mẹta, ó sì gba àwọn ìlú tí wọ́n ti gbà ní ìgbà ayé Jehoahasi, baba rẹ̀ pada.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 13